Eni ti ko kawe mewa jade ko le sise Fijilante – Ganzallo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 6, 2017

Eni ti ko kawe mewa jade ko le sise Fijilante – Ganzallo

Nibi ka sise aabo to monyan lori, odu ni Soji Ganzallo je kii saimo foloko lorileede Naijiria tori pe o ti mu isa aabo rorun pupo leka Fijilante. Ise aabo ilu ti yato patapata si ti atijo, tabi oju tawon eeyan kan le maa fi wo o nitori pe gbogbo nkan lo ni eto ati ilana lati maa fi sise. Eyi to si je ki Oludari ajo eso alaabo Fijilante nipinle Ogun, iyen Ogbeni Soji Ganzallo so pe eni ti ko ba ni iwe mewaa ko le sise won. Kii se eyi nikan ni Ogbeni Ganzallo so, o soro lori awon aseyori e laarin odun kan gege bi oludari Fijilante. Eyi lawon nkan ti Ganzallo ba AWIKONKO so laaro oni ojo Aje Monde, ojo kefa osu kefa, odun 2017.

Ganzallo
AWIKONKO: Oruko yin?
GANZALLO: Olusoji Ganzallo loruko ti iya ati baba mi so mi

AWIKONKO: Nje e lo so die fun wa nipa igbesi aye yin?
GANZALLO: Ti a ba ni ka maa so itan igbesi aye wa nibi ti a ba a de yi, mo ro pe ile a kun die, a fi ka ge peepeepee. Soji Ganzallo wa lati idile Adebayo Ishola Ganzallo ti won je omo bibi ilu Abeokuta lati Ake, nibe ni won bi mi si. Mo lo si ileewe alakobere nilu Ibadan, mo lo si ileewe girama ni Iseyin District Grammar School, nibe ni mo ti lo si ileewe giga poli, iyen Ogun State Polytechnic nigba yen, to ti wa di Moshood Abiola Polytechnic bayii. Leyin yen ni mo lo si yunifasiti ipinle Ogun, Ogun State University, OSU ko too di pe mo bere sii sise. Mo ti wa leni ise ijoba, iyen Ogun State Agricultural Development Programme ti a mo si OGADEP ko to o di pe mo kuro nibe lati tun lo keko loke okun nipa imo aabo, ti mo wa fi n sise se lonii. Igba ti mo de ni mo wa di eni to n darapo mo ajo Fijilante, iyen Vigilante Service of Ogun State, VSO ti a da a sile lodun 2011. Mo bere lati ibi ka maa sise aabo ati alukoro ajo yi, ko to o di pe mo wa fi gun oke agba lati di adari ipinle Ogun, iyen State Commander ni ojo kejila osu karun odun 2016, May 12 2016. Ti a ba ni ka wo o daadaa, mo sese pe odun kan ni bayii.

AWIKONKO: Ki lo fa a to je pe nigba ti e de lati oke okun nibi ti e ti lo ko nipa eto aabo, to je pe eto aabo nipa Fijilante le gbajumo, ti kii se olopaa tabi soja?
GANZALLO: E se e, ti e ba wo igbesi aye mi daadaa, igbesi aye mi bere lori ki n maa sin awon eeyan mi. Nigba ti mo w anile eko, mo je oludari ti a mo si aare egbe awon akekoo Public Administration. Mo fe ki n maa sin awon eeyan mi lawujo ibi ti mo ba wa. Ko to o di pe mo lo ko eko nipa eto aabo, mo ti n sise pelu olopaa, eyi ti a mo si Police Community Relations Committee to je ajosepo awon araalu atawon olopaa. Ti a ba wo daadaa ni gbogbo igba temi bere pelu won, ajosepo araalu pelu olopaa ko dan monran rara, won o ri olopaa gege bi eeyan rere. Awon ise ti mo yan laayo niyen nigba ti mo wonu egbe PCRC lati ri pe a se atunse pelu awon elegbe mi ti a jo n sise papo nigba yen. Atigba yen naa ni won ti fi mi si ipo lati yanju aawo to wa laarin to wa laarin awon Fijilante to wa nipinle Ogun, tori pe se ni won pin si orisi mewaa. A ni lati ko won papo sona kan. Nigba ti mo ti keko nipa aabo, mo wa a ri gege bi ojuse mi fun ipinle mi to je ipinle Ogun lati ri pe aabo to peye fese mule ni gbogbo awon igberiko. Ti e ba wo ise Fijilante, e e ri pe ise aabo awaarawa, iyen grassroot security la n se, ti mo fi wa bere sii se ise aabo, to je pe ibi ise Fijilante ni mo wa a yan laayo lati bere. Ki wa a se pe Fijilante nikan, ti e ba ti wo o daadaa, e e ri pe ati olopaa, ati soja ati sifudifensi patapata ni mo n ba ni ajosepo lori oro aabo. Gbogbo awon eka to n sise aabo nipinle Ogun ati kaakiri orileede Naijiria ni Soji Ganzallo n ba se papo lati rii pe ilosiwaju eto aabo to pe ye wa nipinle Ogun.

AWIKONKO: E je ka wo o, awon won gan an ni a le pe ni Fijilante?
Olusoji Ganzallo
GANZALLO: E se, ninu oro ti mo n so saaju yi, mo ti soro nipa Fijilante. E je ki n so bi Fijilante se je gan an ni pato. Fijilante ni agbofinro to wa laarin awon eeyan wa, to n sise laarin awon eeyan wa lati je ki aabo pe ye. Bi nkankan ba sele lawujo wa, awon to n gbe be, ti won go ede, ti won mo oju ile, awon tawon eeyan wa fokan tan, awon ni won maa koko fi to leti, awon yi la mo si Fijilante, to je pe won wa laarin awon eeyan wa. Ifokanbale wa fawon eeyan wa to je pe bi won ba so fun won nipa nkan to n sele lawujo, ko se ni to le lo ta a, tori won jo n gbe ni. A mo ara wa. Ti awon kolorosi eeyan ba wo agbegbe kan, ti a ba ni ka wo o daadaa, awon to je Fijilante ni won ma a koko mo pe ajeji leni yi, ki i ba wa gbe teletele, ise Fijilante gangan niyen, lati ri i pe won n mojuto aabo to wa ni gbogbo agbegbe wa. Ise aabo to pe ye ni igberiko, ni aarin ilu wa, to je pe awon to n ba wa gbe, ti a jo n sun, ti a jo n ji, awon ni Fijilante, to je pe won n mojuto aabo wa, to je pe ta a ba ri nkankan to ku die kaato lori oro aabo, a le sare pe won lati fi to won leti, ti won a si se nkan to to, ati ohun to ye lesekese, ti kii se pe bo ya a fe e duro dola tabi ose to m bo, to je pe a le ri lati ba soro, won kii se awon to jinna si wa rara. Olopaa ti won gbe wa lati Kano, to n je Danladi, nigba to de ipinle Ogun ni bi, e o le so pe bi awon eeyan wa se maa gba ni won se maa gba eni to n ba won gbele. Ki won to o sunmo, won a koko so daadaa, pe se eleyi se e sunmo, sugbon oro ti ajo Fijilante ko ri bee.

AWIKONKO: Awon ode wa laye igba kan, se ka so pe awon ode aye igba yen ni won wa di Fijilante nipa olaju to de bayii ni, abi iyato wa laari ode ati Fijilante ni ka so?
GANZALLO: E se, ta a ba ni ka wo ise ti Olorun koko da nigba to da ile aye, ise ode ni. Nigba ti Olorun da awon eeyan sinu ogba Edeeni, Olorun fi won so ara won, ibe ni ise ode ti koko bere. Gbogbo ode ti a n so yi, emi gan an bi mo se n baa yin soro yi, olori oga ode ni mi, Olopaa, ode ni; Soja, ode ni; Sifudifensi, ode ni; ise ode ni gbogbo wa jo n se, o kan wa yato si ara won ni. A o le wa a fi oju ti atijo wo o pe se bi ode ni, ode aperan wa, ode to n so eeyan lawa je, awa kii se ode apaayan. Ode ti a n se ni lati se ode awon kolorosi lawujo wa, iyen awon odaran, obaluje tabi awon ti won le ba aabo wa je lawa n se lati mu won. Lori oro ti e beere, ise ode lasiko igba yen, tawon baba wa n so odi ilu, igba yen, e e rii pe bi won ba n so oja to tobi repete, o le je enikan soso lo maa wa nibe, awon eeyan a wa maa beere pe bawo ni baba agbalagba yi se n so oja to tobi too yi, o ni bi won se n se e, o ni ogbon ti won n da si. Ise ode naa ni won n se. Ise ode yi naa lo dagba soke, lo gberu, ni gbogbo eka to wa n yo jade ninu fi bere sii yo jade, eyi ti Fijilante ko gbeyin ninu e. Ise ode ni ode n je.
AWIKONKO: Nje ogbon tawon baba wa n lo lati so odiidi ilu laye igba yen leyin Fijilante naa n lo lasiko yi, abi bawo leyin se n se ti yin lati fi maa so ilu gege bi ohun amusagbara?
GANZALLO: Mo ti so saaju pe mo lo soke okun lori oro aabo, oro aabo ti koja wi pe a n de igbadi, onde, a n se oogun lati so ilu. O ti koja be. Awon ti won n digun wa ba wa laariin ilu, awon ti won n jaw a lole, awon naa n soogun. To ba wa a je oogun la wa ni a fe e gbekele lati maa fi sise ode, se e rii pe a a fe mehe die. O ti yato. Ona igbalode la fi n sise aabo lasiko yi, kii se pe ka maa di igbadi mora tabi onde mora kaakiri.

AWIKONKO: Awon olopaa ko nigbagbo pe oogun wa, nje eyin Fijilante nigbagbo pe oogun wa?
GANZALLO: A maa n tan ara wa je lorileede ti a wa yi ni, awon ti e n so pe won ko nigbagbo pe oogun wa yi naa n se oogun. Ti a ba wo o daadaa, a ti ri eni to je pe Pasito ni, to je pe o n kede igbagbo fawon eeyan, sugbon nigba ti isele sele, ti won tu ara e, won ba oogun lara e. E so fun mi, se ko nigbagbo ninu oogun lo n di mo ara kaakiri, abi bawo lo se de ara e? Bee naa ni ti elesin keji naa, iyen awon Musulumi ti a mo. Awon te n soro won yi naa, ti won ba n lo soju oogun, opolopo n de nnkan mora ki won to o lo. Bi a ba so pe ko soogun, a n puro tan ara wa je ni. Emi o le baayan so pe ko soogun o, sugbon ofin ile wa ko fese e mule pe oogun wa. Ti m ba so pe eni kan lu mi ni nkan, to mu mi maa wu awon iwa kan, ko si ofin to fese e mule pe nkankan wa ti won le fi lumi to le mu mi maa wu iru iwa bee. Ona ti won maa fi to ni ona igbalode, ki won gbe onitohun lo sileewosan, ki won si wo bawo lo se je, kini nkan yen se sele sii, ohun ni ona ti a mo laye taa wa niisinyi. Ohun lo fa to fi je pe ijoba ko gbagbo pe oogun wa, a o le lo sile ejo lati lo maa rojo pe oogun lo fi na mi, o ni lati le fese e mule ni ona iwadii tigbalode pe nnkan to fi na mi yen lo sise yi ti o de le nira die lati se, lo je kawon eeyan maa wo pe ko soogun. Sugbon bi mo se jokoo ti yin, emi mo pe oogun wa o, ka ma so pe ko soogun.

AWIKONKO: Kinni a le pe gege bi aseyori yin laarin odun kan yi?
GANZALLO: E se pupo. Mo dupe lowo Olorun alaaye to gba wa laye, to si fun wa ni alaafia pipe lati le sin ipinle ati orileede wa Naijiria. Lenu odun kan ti mo di oga agba ileese Fijilante nipinle Ogun yi, ee ri wi pe iwuwasi awon Fijilante, mo ti gbiyanju lati yi pada lopolopo lati ri wi pe gbogbo ise ta ba n se, a gbodo se pelu ofin nitori pe eto awon eeyan wa labe ofin wa nibe, a o gbodo te awon eeyan wa loju mole. E e ri wi pe bi Fijilante se n sise ti yato si tigba kan, ko si pe bi Fijilante ba mu enikan, o maa so pe won n lu oun tabi won fi iya aito je oun tabi won lo ti oun mo ibi kan. Gbogbo iwa bee ti kase nile ninu Fijilante. Gbara ti mo ti di oga agba pata ni mo ti jade lo kaakiri gbogbo ibi tie ka wa wa lati ri pe ko sibi kan ti won n pe ni seeli nibi ti won le ti eeyan mo ni gbogbo eka ti a ni nipinle Ogun. Ti won ba ti mu eeyan, a fi ki won lo fa a le olopaa lowo. Ti e ba wo o lona keji, e e ri pe imura awon Fijilante lenu igba ti mo debe yi ti yato si bi won se n mura tele. Aso buraun (brown) la n wo tele, aso to gba idoti ni, sugbon a o tun gbodo wa a ri wa gege bi onidoti eeyan, lati fi way ii pada, e e ri pe iwoso won ti yato si tele, won ti n mo yato, bi won se n wo bata naa ti yato. A tun ti wa n gba awon eeyan kun awon ti a ti ni tele, kii sii se pe a n gba awon eeyan ti o loye. Eni to iwe eri to kere ju ni eni to ni iwe mewaa, kii waa se iwe mewaa lasan, o gbodo yanranti. Kii se pe pe boya mo kawe mewaa, mo wa feeli, Fijilante lo ku ti mo wa fe e se, ko ri bee. Idanilekoo loorekoore la n se fawon eeyan wa lati ri pe a ko won lawon nkan to ye ki won mo lati sise won bo ti to ati bo ti ye. Lasiko mi niwonba odun kan to koja yi, bi eemefa la ti se idanileko ni ileewe wa. Asiko ti mo di oga agba yi ni a da ileewe Fijilante sile, ti a pe ni Vijilante Academy to wa nilu Ilaro nibi ti a ti n ko awon eeyan leko. Ijoba ipinle Ogun lo si fun wa nibi ti a n lo, ti won si fun wa lawon nnkan to ye ka ni, eyi to n mu ise rorun fun wa. A tun n ran awon eeyan wa jade sita. A ti se idanileko alapapo olosekan gbako pelu awon Sifudifensi, a ti se pelu awon olopaa to je ppe awon olopaa ni won wa si ile eko wa lati wa da awon eeyan wa lekoo lori oro aabo. Leyin ti mo debe, mo ti se igbega fawon oga kaakiri ti a fi kun ipo won, opo won la so di apase, (director) ni gbogbo awon eka ti a ni nipinle Ogun. Awon oga agba lekun kaakiri, iyen Zonal Commander la tun ti ro lagbara ju ti tele lo lati le sise bo ti to ati bo ti ye. Leyin ti mo de be ni won tun da ijoba ibile idagbasoke, LCDA ti won yo lara ijoba ibile ogun ti a ni tele sile, lasiko yi ni mo ti yan awon alakoso sibe kaakiri. Ti e ba tun wo o daadaa, laarin odun kan yi, a ti sise takuntakun pelu awon olopaa lati sise papo ko awon kolorosi eeyan lawujo wa, paapaa awon adigunjale ti won ko je ka gbadun lowo wa ti te, awon to wa ni tesan ti wa nibe, tawon min in si ti foju bale ejo. Awon ise ti a ti seyin ko see fenuso tan, eyi lo je ki ijobba ipinle Ogun funra e kan saara si wa pe ise la n se.

Lakoko idanilekoo  to waye laipe yi
AWIKONKO: Ko pe ti e di oga agba ni igbakeji yin naa dide pe oun fee kuro lati da egbe Fijilante miran sile, nje e o ti e ri won gege bi orogun?
GANZALLO: E se o. Emi o ti e ri won rara depodepo pe maa mu won gege bi orogun. Ti a ba ni ka wo o daadaa latigba ti won ti pe ara won ni nnkan ti won n je, e so fun mi, araalu meloo lo gburo won. O di ole meloo ni won ti mu, ijoba wo lo mo won, araalu meloo lo mo won, awon wo lo ti gba won lati gbe ise fun won ti okan won si bale lori ise ti won gbe fun won? Emi o ro pe o ye ka ti e la ara wa loogun lori eleyi rara. Ise ti a mu lokunkundun lati se ni aabo awon eeyan wa, mi o ri won bi orogun rara. Ise ti a gbe siwaju, tijoba gbe le wa lowo, tawon eeyan wag be le wa lowo lawa n se, ki Olorun ko ran wa lowo.

AWIKONKO: Nje e ti e se idanilekoo fawon eeyan yin?
GANZALLO: O wa daadaa, tori e ni mo se soro nipa ileeko ti a sese da sile, ti a si n pe awon olopaa lati wa fun awa Fijilante ni idanilekoo. Ise yi, ise to lagbara ni. Kii se gbogbo omo egbe Fijilante lo n gbe ibon, sugbon iwonba awon to n gbebon gbodo gba idanilekoo to to ati eyi to ye nitori ohun ija ti won gbe dani yen, lati fi daabo bo awon eeyan wa ni, ko gbodo tun je ohun to gbodo se awon eeyan wa lose. Idi ni yen ti idanilekoo fi n waye ni gbogbo igba.

AWIKONKO: Kinni iyato to wa laarin Fijilante okunrin ati Fijilante obinrin?
GANZALLO: Ise kan naa ni won jo se, ati okunrin ati obinrin, ko si iyato laarin won. Ise kan naa la jo n se. ise ti okunrin ba se naa ni obinrin maa se.

AWIKONKO: E ti so nipa awon aseyori yin, sugbon ki a to o le ri nkan toka si gege bi aseyori, o gbodo lawon ipenija kan. Ki ni e le so gege bi ipenija ti e n ba pade?
Lakoko idanilekoo
GANZALLO: Looto ni, e se. Ipenija ti a ni ni ti aini owo to to, eyi to n ba gbogbo awon ijoba wa finra. Awon nkan to ye ka ri gba lati owo ijoba lati fi se awon nnkan ti a fee se. Aini owo ni ko je ki a le e awon nnkan min in. Ti e ba wo gbogbo awon oko wa ti a n lo, ti a n pe ni patrol vehicle yi lawon oko ti a ti gba lati odun 2011, to je pe won ti gbo, won ti denu kole. Ara ipenija ti a ni niyen, sugbon a tiraka lati tun won se, won ti pada senu ise, eyi naa tun je lara awon aseyori ti mi o ranti menuba. Ipenija nla to daju ni ti ainito owo. Awon oko to ye ka maa fi sise ni ko to, bee naa ni ti awon irinse to ye ka lo lati fi koju awon kolorosi eeyan ni ko si. Bakan naa ti e ba wo, ijoba ko lo n san owo gbogbo awon osise Fijilante ti a ni nipinle Ogun, iwonba lawon to n gbowo ninu won. funra wa la n tiraka lati san owo fawon toku, awon to n gbese fun wa, owo ta n ri nibe la fi n sanwo fun won, sugbon Olorun n ti wa leyin lati koju won.

AWIKONKO: Ki lawon ijiya to wa fawon osise yin to sise se?
GANZALLO: Gbogbo idanilekoo ti a ni a n se fawon eeyan wa, awon kan wa ti a pe ni orientation programme lati maa fi ran won leti awon ilana ati ofin (code of conduct) ajo Fijilante, eyi to so nipa bi won se gbodo huwa, awon nkan to ye ki won se atawon nkan ti won o gbodo se. a rii pe a koko se awon nkan yen fun won lati ran won leti ise won lawujo. Leyin ti a ti se awon nkan won yi tan, a a waa ri pe ko seni to maa wa so pe oun ko mo awon nnkan to ye. A tun ti way an awon kan to je pe awon ni won wa nidi ibi ti won ti n ye ejo awon eeyan wo, ti won si n so awon ijiya to to fun iru awon eeyan bee. Eni to ye ka da duro fungba die, iyen suspension, a a lo, eni to ye ka le danu patapata, a a lo, eni to ye ka ro loye, a a se. ti e ba ri lenu ojo meta yi, e e ri pe e o le gburo Fijilante pe ko wu awon iwa ti ko bojumu lawujo, gege bo se wopo tele.

AWIKONKO: Bawo le se n fun ara yin nisinmi?
GANZALLO: Ko ma si isinmi rara fun mi. ti m ba ti debi ise laaro, o tun di ale patapata ki n to o lo sile, ale ti m bat un lo sile naa, ero ibanisoro mi o gbodo ku, o gbodo wa legbe mi niseju-iseju ni, nitori pe bi won ba pe mi pe won ni ipenija nibikibi, mo gbodo pe awon oga to wa lagbegbe naa lati lo o ba won. Bi mo sun naa, oorun aisundokan ko si. Ojo Aiku Sannde ni mo maa n fi sinmi, ti m ba ti se tan nile ijosin, maa wa sibise, ise ojo yen kii dabi taarin ose. Ti m ba ti wa sibi ise yi, ori aga to wa ni ofiisi mi ni mo maa roar fegbe lele si lati sinmi die. Leyin wakati meta maa sese lo sile lati lo ba awon ebi mi sere, ti maa si gbe won jade lo sibi to ba wu mi. Asiko yen ni mo maa n ri aaye lati ba won sere, ti a si soro molebi, oro baba somo, oko si aya.

AWIKONKO: Idibo odun 2019 ti n kan ilekun lati wole bayii, ki ni imurasile Fijilante?
GANZALLO: Imurasile Fijilante atawon osise alaabo ni lati rii pe a so akiti mo apa lati ko gbogbo awon kolorosi eeyan to wa ni awujo wa to le fee ba oselu awaarawa yi je, a pale won mo. Awon kan wa to je pe asiko oselu yi won maa lo ko ibon wole, ti won a lo yo ada, ti won a lo ko awon ohun ija oloro lati lo maa fi sose fun awon oloselu alatako won tabi awon ti won ba n ba ara won dupo. A ti mura sile lati se ohun to to ati ohun to ye. Nkan to sele ni pe ko si eyi to kan wa pelu oro oselu. Osise alaabo kankan ko gbodo fara mo egbe oselu kankan, a gbodo rii daju pe aabo to peye wa fawon araalu lasiko idibo. Okan awon araalu gbodo bale pe asiko to m bo yi, ko nii si wahala fun won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI