E gbo ki lo se JiganMawojue? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 3, 2017

E gbo ki lo se JiganMawojue?

Ko seni to ri gbajumo sorosoro ti won n pe ni Hammed Sanni topo mo si Jiganmawojue, to kose labe agba sorosoro nni, Oloye Sunday Ogunsola Tantala bo se n ka guo-guo kaakiri igboro yoo mo pe nnkan n se e.

Jigan
Bawon kan se n so pe ironu owo lo n se e, bee lawon kan n so pe onikaluku lo ni akoko to maa fi n ronu ayipada rere laye e. sugbon gege bi AWIKONKO se gbo, won lokunrin naa sese padanu iya kan soso to ni ni.

Ironu iku iya naa lo si lokan nitori ti won so pe ojiji ni kina naa ba. Min-wai, iya ti JiganMawojue tori e ronu kii se omokekere rara, won ni iya naa ti won pe oruko e ni Arabinrin Sariyu Titilola Anike Sanni ku odun kan soso ko pe ogorin, iyen 80years, odun mokandinlogorin, 79years ni won pe ojo ori mama yi.

Looto lo le je pe iya naa tete ku nitori AWIKONKO gbo pe ko tii pe ni iya naa padanu okan lara awon omo e obinrin, ojo karun osu kerin odun yi la gbo pe omo iya yi to n je Taiwo Olorode Aminu ku. Ironu iku omo e yi la gbo pe o gee mi mama kuru, talo le padanu omo ki ara ma taa, Edumare ma je ka foju sunkun omo wa, Amin.

Ni nnkan bi aago kan aabo osan Ojoru Wesde to koja niya JiganMawojue dagbere faye ni osibitu ijoba apapo Federal Medical Centre to wa ni Idi Aba, Abeokuta ipinle Ogun nibi to ti n gba itoju ki olojo too de.

AWIKONKO tun rii gbo pe owo ti yoo fi soku iya naa lo tun je ironu fun un nitori pe ko ronu e tele, o si sese lo owo fun nkankan laipe yi ni.

Lojo keji, iyen Tosde ni won ti te mama naa si afefe rere ni nnkan bi aago mokanla aabo aaro nilana Musulumi nile e to wa ladugbo Mango, Oke-Ata, Abeokuta.

E waa gbo o, Ojobo Tosde to m bo lohun la gbo pe won yoo se ojo mejo iya naa nibi ti won sin in si, iyen Mango, Oke-Ata. E ni to ba ri Jigan ko so fun un pe iku iya e ko lowo aye ninu o, olojo lo de nitori pe bi iku ba fee de, a a fi nkan kan se sababi ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI