Bisoobu Bala |
Iyalenu loro ojise
Olorun kan ti won pe ni Mgr Marie Menoit Balla to je Bisoobu Bafia lorileede
Cameroon si n je fawon araalu lori bi won se so pe se lo deede lo be sodo kan
ti won pe ni Odo Sanaga lagbegbe Ebebda.
Gege bi AWIKONKO se
gbo, Osan Ojoru Wesde to koja yi ni won so pe Bisoobu Menoit Balla paaki ojo
jiipu ti won pe ni Land Cruiser SUV, eyi ti nomba idanimo e je CE 9503V sori
afara Ebebda, to si be sinu odo naa.
Awon nkan ti won ba ninu moto e |
Awon kan to ri oko
naa lo duro lati ye e wo, ti won si ri kaadi idanimo, iwe irinna atawon iwe oko
naa ninu e, eyi to je ki won gbagbo pe se lokunrin naa be sodo.
Lesekese ti agbarijo
awon eeyan soosi ti okunrin naa wa, iyen ijo Katoliiki (Catholic) ti gbo ni won
ti bere sii wa lati mo ibi to wa.
Nnkan to je ki won
mo wi pe se lokunrin naa deede be somi ni iwe ti won ri tokunrin naa ko lati je
ki won mo pe oun wa ninu omi. Eyi lo mu ki won tete ranse sawon agbofinro
atijoba ipinle naa.
Ibi isele naa |
Gbara toro isele naa
ti kan Gomina aaringbungbun ekun naa, Naseri Paul Bea lo ti gbera lati wa mu
oju aje koniso. Bakanna ni eni to je Divisioner Officer Ebebda so fawon
akoroyin pe looto nisele naa, atipe ko si nkan to se oko Bisoobu naa.
No comments:
Post a Comment