Beeyan ba wa nile ejo
to n ja feto awon eeyan nile Europe lojo Isegun Tusde to koja yi nigba tile ejo
pase pe ki ileewosan dawo itoju ti won n se fun Charlie to je omo ose mejo pere
ti won so pe aarun kan ti won poruko e ni mitochondrial
n yo lenu, to ri bawon obi e se n gbera sanle pe ki won foju aanu woo mo awon,
aanu abiyamo yoo se.
Charlie |
AWIKONKO gbo pe gbara
ti won bi omo naa ni won ti sakiyesi pe ara e ko da, to si nilo itoju to pe ye,
won ni leyin ose mejo ni won ti won bi omo naa ni won gba eje e lati yee wo, ti
won si sakiyesi pe aarun naa wa lara e.
Latigba naa ni won ni
won ti bere sii toro owo fun un lati fi toju e, to je pe awon eeyan ti fomo naa
ni opolopo milionu dola lati le je ki awon dokita toju e lona ara oto.
Sugbon iyalenu lo je
owo ti won fi n toju omo ti won ni bi won ba toju e ju bee lo, o see se ko ku,
ti yoo si tun je ki won padanu owo ti won tun le fi se awon mi in to nilo e
lanfaani, owo naa ni won ni ko niye.
Awon obi omo yi,
Chris Gard ati Connie Yates so pe ki ileejo fun omo won, Charlie lanfaani lati
tubo gba itoju, ati pe awon oogun kan wa tomo naa si le maa lo yato si pe o wa
nile iwosan, sugbon gbogbo ebe ti won ni won n be ni ko wo eti adajo lojo naa.
Ileejo so pe se lo
dabi eni pe won kan n fiya je omo naa lasan ni, tori pe irora to n je lori
beedi to wa po ju oju ti won fi n woo lo, ati pe awon ero ti won fi gbe emi e
duro ko le je ko pe laye.
Awon obi e |
O wa pase pe ki
ileewosan tomo naa wa yo awon ero ti won fi gbemi omo naa duro kuro lara e, ki won
si je ko maa ba ti e lo.
Agbenuso fun
ileewosan to ti n toju omo kekere yi lati osu kewaa odun to koja so pe kawon
obi omo naa lo farabale nitori pe kii se esekese ti ileejo ti pase naa ni won
yoo yo awon ero naa kuro lara, o ni iye ojo gege bo ti se wa ninu akosile.
O ni suuru loro naa
gba ati pe igbese n lo lowolati tubo du emi Charlie. Ohun taa gbo ni pe milionu
kan ataabo owo Euro ni won ti fi ta Charlie lore fun itoju e pelu akosile
ileefowopamo si ti won pe ni GoFundMe.
No comments:
Post a Comment