Aye ma le o: Esther ni egbon baba oun lo foun l’aje - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 20, 2017

Aye ma le o: Esther ni egbon baba oun lo foun l’aje

Sugbon obinrin naa niro ni

Beeyan ba wa nibi ti omodebinrin omodun mejila, Esther Emmanuel ti n tako egbon baba e, Arabinrin Hannah to je omo bibi ipinle Benue lose to koja pe obinrin naa lo foun laje ko nii se iyemeji pe looto ni pelu awon oro tomo naa n so jade.

Esther Emmanuel
Ori eto Awodi Oke ti Alaaji Moruph Adegboyega topo mo si Omodo Agba maa n nileese redio Family FM to wa nilu Abeokuta lojo Aje Monde laago mejo si mewaa ale ni Esther ti soro naa.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ni nnkan bi osu keta odun to koja ni Esther so pe egbon baba oun, Hannah yi, eni tawon eeyan mo si iya Ruth foun atawon aburo oun ni raisi je, to si je pe okan oun ko je ounje lojo naa, sugbon agidi lobinrin naa fi foun je.

Ni nnkan bi aago meta osan loro ounje naa sele nigba ti won ni Esther atawon aburo e, pelu mama e loo ki obinrin naa nile to n gbe, ti won pe ni ile Omo-Ekun lagbegbe Apakila, Camp nilu Abeokuta.

Esther so pe nigba to di nnkan bi aago kan oru loun rii pe eye kan ba le oju ferese yara tawon sun si to si n ke, leyin naa loun si di eye nla, loju ese lo so pe oun ba ara oun laarin awon aje, to so pe eyin ileewe girama Salau Abiola to wa nitosi Osiele lawon ti n sepade naa legbe odo kan to wa nibe.

Omodebinrin naa so pe boun se de be loun ri awon agbaagba ladugbo tawon n gbe, tie nu si ya oun, o ni ko pe ni iya Ruth to pe ni egbon baba e yi foun ni abere meji kan pe koun gbee min, abere ofofo ati abere bo-enu-bo-enu. O ni abere akoko lo n sise fun pe koun wa maa so gbogbo nkan to n lo ninu ebi oun, abere keji sise fun pe oun ko gbodo so fenikan nnkan tawon n se ninu ipade naa.

Nigba to n daruko awon ti won jo wa ninu egbe aje naa, o so pe Iya Dudu, Iya Qoyum, Iya Katangoa, Iyale Omo Ekun to n ta worobo (Provision), Iya Ibo, atawon min in. o ni kii se pe oun fee bawon loruko je.

O ni ikilo ti won se foun ni pe ojo toun ba so loun maa ku, to si je pe atigba naa loun ti n bawon segbe aje naa papo, ti ko si seni to mo nnkan ladugbo tabi enikeni ninu ebi oun.

Esther nigba to n soro tun ko orin ti won maa n ko ninu ipade naa pe “awon anjonu tun de, awon aje tun de, won fe wa soro…” tie nu si ya gbogbo awon to wa nibe. O ni Asake loruko ti won foun ninu egbe aje naa.

Gege bi a se gbo, kii se pe omo ti won n pe ni Esther yi deede maa ka sita fawon eeyan, bi ko se pe eni kan ti won ni won loo kolu, to je ojise Olorun, sugbon ti won so pe awon ogun orun lo ko obinrin iranse Olorun ti won ni ki igi nla wo pa naa yo ni nnkan bi ose merin seyin.

O ni bo tile je pe awon da ise obinrin naa ru, tawon si ti gba opolo awon omo e sinu ikokoo, sugbon eyi to bu awon lowo ni ti ise iranse e tawon fee kolu, tawon si fee paa lo bu awon lowo.

Leyin isele naa la gbo pe Esther ti won ni ipele karun nileewe alakobere kan taa foruko bo lasiri dubule aisan, to si je pe gbogbo ileewosan ti won n gbee lo ni won ko ri nkan to n se e, ko too di pe won gbee lo si soosi kerubu ati serafu kan to wa ladugbo Camp ti won gbe, nibe ni won so pe emi orun ti ba le Ruth.

Soosi ti won ni won gbe Esther lo ni won ni olori ijo naa ti se awon akanse ise kan fun un, to si so pe ki Esther lo sun siwaju pepe digba ti yoo fi laaro ojo keji, sugbon se la gbo pe ko ju bii iseju meedogun tomo naa sun, lo sare jade pe oun ko le sun sibe yen mo.

Nibe ni won ni obinrin olori ijo naa ti so pe kawon to wa nitosi sun siwaju nitori pe oun fee beere awon oro kan lowo Esther, won ni omo yi ko koko fee jewo, sugbon nigba to ya lo bere sii ka pe aje loun tele, egbon baba oun lo si foun laje naa.

Hannah, Iya Ruth
Saaju asiko yi la gbo pe iya Esther naa la ala wi pe nibi toun ati Esther sun si lawon obinrin meji kan ti yo sawon ti won so pe eru awon to wa lowo Esther lawon waa gba, loju ala naa lobinrin naa ti n na omo e pe ko ko awon eru owo e sile fawon eeyan naa, sugbon tomo naa ko soro titi to fi taji.

Eyi lo mu ki iya Esther loo ro ala naa folori ijo sele yi, ki won too sise naa fun, to si bere sii ka bi eye orofo.

Esther so pe ko pe toun denu egbe naa loun mu ejo iya aladura kan lo pe o na oun, ki won ba oun je e niya, ise iranse ati oja tobinrin naa n ta lo so pe won soo ti won si soo sinu ira pe ko nii gberi mo. Bee lo so pe iya Ruth ni koun mu ogo baba oun ati ti aburo baba oun ti won n pe ni baba Iyanpa lawon ko sinu ikoko ti won si gbee lo sidi ogede tawon ti n sepade.

Omo naa so pe esun ti iya Ruth so pe baba oun se e ni pe gbogbo igba toun ba ti beere nkan lowo e lo maa n so pe ko si, to si so pe oun ti ogo e saaju e, lo fi mu ogo e so sinu ikoko, to si gbee sidi ogede.

Bakan naa lo so pe gbogbo ojo Isegun Tusde ati Ojoru Wesde lawon maa n sepade naa, ati pe ojo maa n pa won wole lojo tojo ba kawon mo ipade, o lawon obi oun kii mo tori pe won ti sun lo ni ti won.

Esther tun so siwaju pe inu aso alawo buluu kan ti won foun ninu ipade ni agbara oun wa, sugbon nigba tawon wa a debi ti won n ko aso agbara si leyin ti asiri oun tu, awon ko bawon aso nibe mo, won ti ko o kuro.

Bee lo so pe bo tile je pe oun ti mu eje eeyan, toun si ti jeran eeyan, sugbon oun ko tii fa eeyan kale toun naa le fi dajo, kawon egbe oun si mu eje won, won tun jeran won. o lojo ti won so pe koun fa baba ati mama kale lati fi won dajo, se loun so pe ko seese, ki won si ni suuru foun.

O lawon ti pinu lati mu nkan omokunrin baba oun, sugbon ti ko seese fun won nitori pe eni tawon lo awo e lati fi sise naa, pabo lo ja si nitori baba oun ko wo ibe. O tesiwaju pe saaju koun too de ilu Abeokuta ni iya Ruth ti pa awon egbon oun atawon aburo ouun pelu iya baba oun ko too di pe won fa oun wonu egbe, o ni gbogbo nkan ti won ti seyin ni won so foun ninu egbe.

Baba Esther omodun mejila yi, Ogbeni Emmanuel nigba toun n soro nipa awon oro tomo e n so jade, o so pe iyalenu lo si n je foun nitori pe oun ko tie rii ro pe iru e le sele si sakani oun, o loun kan n gbo o ni.

Okunrin naa loun ko ni ero telifisan nile, toun ko ba so pe bo ya awon fiimu to n wo lo fa komoun maa so awon oro yi. O loun ti ni telifisan nigba kan ri, koun too de ilu Abeokuta, o si ti to odun marun seyin ti telifisan naa ti baje. O lawon fiimu onigbagbo loun maa n wo, kii se tawon Nollywood.

O ni lojo toun maa gbo, o sese de lati ibi ise oko toun se ni, ibi toun ti fee jeun ni iya Esther ti so foun pe omo oun n ka, tomo naa si so awon oro naa foun, o lawon oro to n so ko pe meji fawon to n soo fun.

Emmanuel so pe oun ati egbo oun iya Ruth yi ko ija ti tele, awon ko si ni gbolohun aso ri nitori pe oun gan an lo se atona oun de Camp toun n gbe, to tun bawon wa ile tawon n gbe, bo tile je pe oun loun san owo ile naa.

Iya Ruth, Arabinrin Hannah tojo ori e ti n sunmo ogota odun nigba toun naa soro lori esun ti won fi kan an pe aje ni, o ni iyalenu loro naa si n je foun nitori pe oun ko mo nkan kan nipa e, ati pe iro ni gbogbo awon oro naa.

O so pe Igede loun, nitori pe Markudi nipinle Benue loun ti wa, o loko oun lo gba ile sile baba ti won n pe ni Omo-Ekun nibi toun n gbe bayii lodun to koja. O ni ise ode (hunter) loko oun n se, sugbon eekookan lo maa n wa sile.

Awon obi Esther
Hannah ni awon eeyan lo so foun pe Esther n fesun kan oun pe aje loun, to si ti so kaakiri aye pe oun loun fun un ni Aje, o loun ko ni aje depo-depo pe oun maa fun un yan laje, kawon eeyan gba oun lowo Esther.

Obinrin naa so pe boya aje dudu ni tabi pupa, oun ko ni aje, oun ko si mo nkan ti won n pe ni aje. O loun ati baba e ko ni ija ti tele, atipe awon obinrin po ladugbo, toun ko si le so pe nnkan tomo naa ri niyi, to fi fesun nla banta-banta bee ka noun.

O loun ko tii loko nigba toun baba Esther kuro nile lodo awon obi won nigba to wa ni kekere, toun si loo toju e, nitori pe inu aisan nla kan lo wa, ti Olorun si se iyanu.

Hannah so pe bo tile je pe oun ko ranti ojo ti omo naa n so pe oun fun un ni raisi je, sugbon oun maa n fawon omo kekere to n gbe lodo oun lounje, toun ko si maa n fe koun maa jeun, komo kan to wa nitosi oun maa wo enu awon.

O ni ko seese koun ni aje, toun ko si fi pa baba e, se oun loun maa wa fi pa omo. O rawo ebe sawon omo Naijiria pe ki won gba oun.

Ohun tawon araadugbo so nigba ti won n bakoroyin wa soro nipa oro naa ni pe, awon oro ti Esther n so kii se iro, ati pe gbogbo awon tomo naa daruko lo je pe iwa won ladugbo ko tako awon oro to n so.

Ohun ti a gbo bayii ni pe Iya Qouyum to je okan lara awon ti Esther daruko pe awon jo wa ninu egbe aje naa ti lo gbe ija ka iya aladura to gba Esther sile mole, to si leri sii pe awon yoo foju e han mabo. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI