Awon olopaa ra ori eeyan ni Sagamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 14, 2017

Awon olopaa ra ori eeyan ni Sagamu

Bi kii ba se ogbon tawon olopaa ipinle Ekoo lo lati fi mu okunrin kan ti won pe oruko e ni Lucien Tosume, eni odun marundinlaadota ti won so pe ko nise meji ju ko ta ori eeyan lo labule kan ti won n pe ni Iraye, nijoba ibile Sagamu, bo ya okunrin yi ko ba ti na papa bora.

Tosume pelu ori eeyan to ta
AWIKONKO gbo pe ojo kerin osu yi lawon olopaa rii mu leyin ti won gbo pe okunrin kan n ta ori ati eya ara eeyan labule naa, ni won se dogbon pe lori aago, ti won si jo duna dura lori iye to fee ta ori gbigbe eeyan.

Ohun taa gbo ni pe egberun lona aadojo (N150,000) naira ni Tosume so pe oun yoo ta ori gbigbe naa jale, sugbon ti won be e si egberun mokanlelogorin (N81,000) naira, to si gba pelu won.

Bi won se san owo naa tan ni won so pe awon fee ri, kawon le tubo jo dowo papo, inu dun to so ibi ti won ti le pade fun won. Ka ni o mo pe awon olopaa ni, ko ba ma ti dawon lohun lojo naa.

Gbara ti won foju kan an ni won ti ko sekeseke sii lowo, ti won si mu lo si tesan won nibi to ti ka gbogbo bo se n sise e lateyin wa.

Tosume
Agbenuso olopaa nipinle Ekoo, Ogbeni Olarinde Famous-Cole so pe awon olopaa lo ogbon ayinike lati ba okunrin naa duna dura lati ra ori eeyan lowo e, to si taa fun won.

Famous-Cole so pe Tosume jewo, o si so pe oun maa n ori eeyan toun ba sese ge ni milionu kan naira fawon to ba fee ra.

Sugbon ni bayii, AWIKONKO gbo pe won ti tare Tosume lo si olu ileese olopaa to wa ni Panti nipinle Ekoo fun iwadii siwaju sii. O wa gbawon araalu lamoran pe ki ri daju pe won n boju to awon omo won daadaa nitori iru awon odaran bii Tosume  yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI