Awon dokito labe asia
egbe won Nigeria Medical Association, NMA eka tipinle Osun ti setan lati lo
dase olojogbogboro sile nitori bi won se so pe ijoba ti dawo owo osu aabo ti
won n san fun won duro.
Awon dokita Osun |
Lojo Isegun Tusde to
koja yi ni agbarijo awon dokita naa bere iwode ifehonu han lati osibitu LAUTECH
to wa ni Osogbo lo si Olaiya atawon igboro kaakiri ilu Osogbo. Nibe ni won tun
ti je kawon araalu mo pe ko si oogun Kankan lawon osibitu kaakiri, bee ni ko si
irinse fawon osise osibitu.
Bo tile je pe ijoba
ipinle naa so pe milionu mewa lati na lori ipese ohun amaye rorun fawon osibitu
ijoba kaakiri ipinle naa, ati awon nkan to le mu irorun ba eto ilera, sugbon
won so pe iro ati oro enu lasan ni.
Alaga egbe naa,
Dokita Tokunbo Olajumoke nigba to n bawon akoroyin soro lakoko ifehonu han naa
so pe ijoba ko pe awon nkan amayederun feto ilera nipinle naa, atipe o pelu
nnkan to sokunfa iku Senato Isiaka Adeleke to ku lojo ketalelogun osu to kerin
odun yi.
Olajumoke so pe
Adeleke ko lo si osibitu ijoba to sun mon on nitori o mo pe ko si irinse to
peye lawon osibitu ijoba, nitori e lo se gba osibitu ibomiran lo lati lo gba
itoju.
O ni bo tile je pe
owo osu aabo lawon dokita n gba, sibe ijoba tun n yo owo ori e pe ninu owo ti
won n fun awon awon to je pe agbara kaka lawon fi n ri owo ounje yo ninu e.
No comments:
Post a Comment