Awon alainimo lo n ba ise wa je – Egbe onifoto - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 10, 2017

Awon alainimo lo n ba ise wa je – Egbe onifoto

Egbe onifoto, ayaworan nipinle Ogun, iyen Ogun State Photographer Association of Nigeria, OGSPAN ti so pe awon alainimo nipa ise naa lo n ba ise won je, to je pe tipatipa lawon fi n ri owo mu lo senu lasiko yi.

Kamera
Fawon to ba n ya foto daadaa tele, ni nnkan bi odun meje si mejo seyin, aadota naira (N50) ni won n ya foto tele, sugbon nigba to ya, won so o di aadorin naira (N70), ko pe sigba naa ni won so o di ogorun naira (N100).

Ni bayii tie to oro aje orileede Naijiria ti denu kole, ti gbogbo nkan ti gbowo lori ni foto yiya ti di aadojo naira (N150), to si je pe o niye ti won maa n gba ti won ba pe won si ode ariya lati wa a ya foto fun won.

Gege bi iwadi to te AWIKONKO lowo lojo Eti Fraide ana yi, egberun mewaa lowo to kere jut awon onifoto n gba lowo awon to ba pe won sode ariya, bii igbeyawo, oku, ayeye ojo ibi, igbeyawo ati bee bee lo, ninu owo yi naa ni won a tun ti ya aworan fidio (video) bi pati naa ba se lo.

Kii se egberun mewaa yi ni gbegede owo ti won n gba lowo awon to ba pe won, sugbon owo ti won n gba niise pelu bi ise ti won maa se ba se ri, to si je pe egberun mewaa lowo to kere ju ti won n gba.

AWIKONKO gbo pe opo awon eeyan ni won ti n ba ise naa je fawon eeyan yi bayii latari owo ti ko to n kan ti won n gba lowo awon to ba pe won. bawon kan se n gba egberun meje, lawon kan n gba egberun marun un, tawon kan ko si maa n gba to yen.

Eyi lo fa to fi je pe awon kan maa n foju eeyan buruku wo awon osise foto naa pe ere ajepajude ni won n je bi won ba so pe awon ko sise ti won ba fi egberun marun lo won pe ki won wa bawon sise nibi pati won, nigba to je pe owo ti ko to nnkan ni won fi n lo won.

Bee awon to n gba owo kekere yi kii se pe iyen tawon naa n gba niyen, sugbon nitori atije ni won se n gba, sugbon tawon miran kii rowo won gba pe lowo to ba pe won sode ariya leyin ti won ba pari ise.

Okan lara awon omo egbe OGSPAN to b”AWIKONKO soro nipa isoro to n koju won nidi ise naa laipe yi, Ogbeni Ibrahim topo mo si Ibromercy so pe awon alaimokan, awon ti ko kose foto ni won ba ise naa je mo awon lowo latari owo ti ko to nkan ti won n gba.

Ibromercy so pe iyen tawon n ra awon irinse tawon n lo ti yato sigba kan, awon irinse bii kamera, pirinta (printer), pepa (paper) atawon n kan min in tawon n lo ti gbowo lori ju ti ateyinwa lo.

O so pe pepa tawon n ra lowo ti ko to egberun mefa tele ti di egberun mokanla bayii; printa tawon n ra lowo ti ko to egberun lona ogbon tele, eyi to kere ju bayi ti to egberun lona aadota; o so pe kamera to kereju ti wo egberun lona ogorun din ni egberun marun naira (N95,000) bayii.

Okunrin naa so pe bo tile je pe kii se ojoojumo lawon n ra irinse, sugbon gbogbo nkan tawon n lo lo nilo atunse to ba baje, owo tawon fi n tun awon nkan naa se ti yato si ti tele, o ti gbowo lori gegere.

Pelu edun okan lokunrin naa fi so pe laipe yi toun fe e lo tun okan lara awon kamera toun n lo se, oju oun leni to fe e ba oun tun un se se pe awon to wa l’Ekoo, to si so pe egberun mejo loun yoo gba jale, to si je pe egberun meta lawon n se e tele.

O ni bawo lawon se maa maa ri iru awon nkan bayii tawon ko nii soro jade sita, ti inu ko ni maa bi awon sawon to n ba ise won je. O so pe nigba tawon ba n ro gbogbo eyi papo, tawon eeyan si n fowo ti ko to nkan lo awon, bawo lawon se fee ri owo jeun, tawon yoo si tun bo ebi won.

O tesiwaju pe oun ko tii ri owo ileewe awon oun san bo tile je pe ileewe ijoba ni won n lo, sugbon owo ti won ni ki won mu wa, oun ko tii ri san, bee lo so pe owo ile si wa nibe, awon eeyan si n rii pe oun n sise laimo pe adojuko tawon n koju nidi ise naa ko se e fenuso.

Ninu iwadi ti AWIKONKO se la ti gbo pe enu awon oloye egbe naa ko ka awon omo egbe, atipe kii se gbogbo awon to n sise naa ni won darapo mo egbe naa latari awon idi kan ttabi omiran.

Awon kan so pe ikowoje tip o ju ninu egbe, bee awon ko ri ipa owo tawon n da sinu egbe naa, to je pe se lawon oloyee maa ko o je, tawon ko ni ri abo e, alo nikan lawon mo.

Ibromercy ti wa rawo ebe sawon araalu pe ki won dakun wo won se laanu, ki won yee ba ise je fun won, latari owo ti won fe maa san fawon ti ko to n kan. O ni egberun mewaa yi, kii se pe owo naa ka awon, sugbon ko si nkan tawon fee se lo je kawon so pe owo naa ni yoo je owo to kere jut awon yoo maa gba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI