Odu ni gbajumo
sorosoro nni, Jeleel Ajayi topo mo si Angel nidi ka gbohun safefe kii saimo
foloko paapaa nileese redio aladani Family FM to wa nilu Abeokuta, okunrin naa
so lori isoro to n koju egbe naa latari awuyewuye ati ikunsinu to n lo laarin
awon omo egbe naa fun ti idibo to m bo ninu osu keje odun yi.
Angel Ajayi |
Ojoru Wesde to koja
yi ni Angel Ajayi so nipa ibi ti ipile naa ti wo wa lakoko to ba AWIKONKO soro
nilu Abeokuta.
Ko tii seni to le so
ibi toro naa maa fori sole si titi di bi a ti n koroyin yi latari wahala ati
awuyewuye to n sele ninu egbe sorosoro, Freelance and Independent Broadcasters’
Association of Nigeria, FIBAN eka tipinle Ogun.
Ko soun meji to n da
wahala ati awuyewuye sile laarin awon omo egbe naa bi ko se ti idibo sipo alaga
to fee waye ninu osu keje to m bo yii, to si ti da ote sile laarin won, to tun
je ki egbe naa pin sona meta bayii.
Okan lara awon omo
egbe naa, eni to so pe oun ni won fee lo fun alaga tele sugbon toun so pe asiko
ko tii to, kawon agbaagba si maa tesiwaju lo naa, digba ti asiko toun yoo fi
de, Jeleel Ajayi topo mo si Angel leni naa.
Okunrin naa ti soko
oro sawon agbaagba pe awon gan an ni igi leyin ogba to n da egbe FIBAN ru,
latari bi enu won ko se ko lati bawon omo keekeeke egbe naa soro, o ni won ko
lenu oro lati pase fawon omoleyin won nitori ote.
O ni nigba toun fee
darapo mo egbe naa, bo tile je pe oun ti n seto lori redio nipinle Ekoo koun
too wa tedo silu Abeokuta, akiyesi toun se ni pe agbekale ote lawon agbaagba
egbe naa fi n ba ara won se po, eyi tawon omo leyin won si n wo awokose e fi
siwawu.
Angel so pe nigba ti
won ti oselu bo oro idibo ni won bere sii fi ote le awon kan kuro, ti won
barawon ja gidi. O ni awon eeyan bii Asamu Akinrinde, Abiodun Muibi, Desmond
Nwachukwu ti se alaga, sugbon o je pe latigba naa ni ote ti bere, ti won ko lo
ife lati ba ara won se, nitori pe odo awon agbalagba lo ye ki ife ti bere kawon
to m bo leyin si maa wo awokose won.
O lawon agba ko fi
ipile rere lele fawon odo to n bo leyin, to je pe seni won a maa binu ara won,
ti won a maa soro ara won leyin, ti won a maa ba ara won loruko je. O so pe
nigba ti Desmond se, ariwo pe o kowo je ni won n pa kiri, to si je pe okunrin
naa ko ri owo ileewe omo e ati ile to n gbe san nigba naa.
Angel lopo awon
agbalagba egbe naa ni ko san owo (dues) ti won maa n san losoosu, o ni nigba
tawon agbaagba ko san owo yi, to je pe won a tun pe de ipade, bawo lawon to n
bo leyin se fe e san ti won, awokose ni won a maa wo. O tesiwaju pe orin pe eni
kan ko se daadaa ni won n pa, ki ni nnkan ti won n wo nigba naa ti won ko le ba
eni naa soro.
Okunrin naa tun so
pe ko ye ki nkan ti won n pe ni faction wa ninu egbe sorosoro rara, nitori pe
se lawon araalu n wo awon gege bi awokose, gege bi ebi to mo nkan tan, ti awon
eto won si n tun opolopo idile se. o loo seni laanu pe awon tawon so pe awon n
tun idile onidile se ni idile ti won gan an o da, toripe FIBAN, idile kan ni.
Ninu oro e, “Ote ti
won n se yi ti poju, won n binu ara won ju, nigba ti eni kan ba joye, ti e maa
ko awon eeyan jo lati dite yo o kuro, ko ye ko ri bee.”
Bee lo tun so pe
nnkan to n da wahala sile ju ni ti aini eto, ilana, agbekale ati ofin to de eto
idibi, “Ni bayii, ti a ba n so nipa awon agbaagba FIBAN, e wo iru idibo to n bo
yi, to ba je pe agbekale kan ti wa tabi atunse agbeyewo agbekale, bii ki won so
pe iwo ti o ba fee jade, o ye ki o ti lo iye odun bayii ninu egbe, tabi ojo ori
e gbodo je odun bayii ki o too dibo.
“Ko si ofin to de
idibo rara, awon omode o le pase idibo, awon agbaagba ni won lase lati pase
idibo, sugbon awon agbaagba kan wa to je pe bi eni ti won o fe ba ti wole, won
a bu ile ipade dani, won ko nii wa sipade mo, o tun die yin odun metta tabi
merinti won bat un ni nnkan se ko tun to yoju, ko ye ko ri bee.”
O so siwaju pe nitori a ti ri owo gba lowo
awon eeyan lo se n dupo ninu egbe, to si je pe se lo ye ki won gbe egbe naa gun
oke agba, o ye kawon ti won pe ara won ni agbalagba jokoo papo lati so asoyepo,
ki won se atunse, sugbon owo ti won n wa ko ni je ki won ronu lo sibe.
O so pe egbe to ti
gbooro ni FIBAN je, sugbon ijoba ko mo won bo se ye, won ko fun won ni owo
(respect) to ye ki won fun won nitori opo awon agbaagba yi gan an ni won maa n
bu ijoba, to si je pe ijoba tawon gan an se, ko se e gbo seti. O laini
idanilekoo lore-koore fawon omo egbe, sugbon ti ko si nitori pe eru kan nii mu nib
u igba eru.
O so pe bo tile je pe oun
kere lati gbawon lamoran, sugbon oun tun gbodo soro pe kawon agbaagba FIBAN lo
tun ijokoo jo tai se atunyewo ati atunse ofin, ti ko ba si ofin tele, ki won lo
gbe ofin maa de gbogbo omo egbe kale, eyi ti yoo tun so nipa eto idibo ninu
egbe. Bee lo ni kawon to n bo leyin naa maa wo awokose rere lara awon agbaagba
ko ma je pe eyi to ku die kaato ni won a maa wo.
No comments:
Post a Comment