Akekoo Paragon to ku si odo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 3, 2017

Akekoo Paragon to ku si odo

Won ni aibikita oludasile ni

Titi di bi a ti n koroyin yi lowo lawon obi akekoo ile eko Paragon to wa lagbegbe Oke Aregba nilu Abeokuta, ti won pe oruko e ni Eniola si fi wa ninu ibanuje lori bi omo naa se ba omi lo, to si ku.

Aworan
Gege bi AWIKONKO se gbo, aaro Ojobo Tosde nisele naa waye niwaju ogba ile eko naa latari ojo to ro mojumo, nigba ti won so pe die lo ku ki odo naa gbe moto kan lo mo.

Won ni iya Eniola lo mu oun ati egbon e lo sileewe laaro ojo naa, sugbon nigba to wa moto e ti nomba idanimo e je LAGOS BDG 460 EA de iwaju ileewe naa nibi ti odo to wa legbe e ti kun de iwaju e, se lawon eeyan bere sii pariwo nigba ti won rii pe odo naa ti gba moto mo obinrin naa lowo.

Ki won too seju pe omi ti wonu moto, o si ti fee mu won de ori, ko too di pe awon toro naa soju e sare lo o yo won, sugbon o seni laanu pe won ko tete ri Eniola yo, bi won se so pe ori tako o.

Leyin bii ogbon iseju ti won ti n wa Eniola ninu odo naa ni won to o sese ri nibi ti odo naa gbe pamo si, lesekese ni won ti sare gbe e lo si osibitu ijoba apapo Federal Medical Center, FMC, Idi-Aba, Abeokuta fu itoju nibi to ti gbemi mi.

Nigba ti won n jeri si isele naa, awon araadugbo naa nigba ti won ba AWIKONKO soro so pe looto ni atipe kii se akoko tiru isele bee maa waye niyen nitori pe opo awon akekoo lodo naa ti gbe lo latigba ti ijoba ti fowo sii pe ki won ko ileewe sibe.

Ohun ti a gbo ni pe ki ijoba too fun oludasile Paragon niwe ase lawon agbaagba adugbo naa ti pe e pe ko ma daba lati fibe se ileewe nitori ewu ojo iwaju fawon eeyan paapaa awon akekoo to maa maa wa sibe, sugbon se ni won so pe ko dahun.

Alaga idagbasoke Oke-Aregba, Ogbeni Owolabi AbdulAkeem nigba toun naa n ba AWIKONKO soro so pe ko si n kan tawon le se si nigba to je pe ijoba gan-gan lo fun oluudasile ileewe naa niwe ase lati kole sori odo lair o ti ewu to wa nibe.

O lorisirisi awon eeyan leka ise ijoba lo ti wa a wo ibi ti ileewe naa wa, ti won si rii pe eti odo lo wa ko too di pe won bu owo lu, ti won si fun un niwe ase pe ko maa base lo. Ko si igbese miran tawon le gbe nigba tijoba funra e ti fowo si.
O wa rawo ebe sijoba ipinle Ogun atawon toro kan pe ki won gba awon lati doola emi awon araalu paapaa awon araadugbo latari bo se je pe ileewe Paragon lo n di ilogeere odo naa lowo, eyi ti ko fi won lokan bale.

Arabinrin Yinka Badmus toun naa je okan lara awon araadugbo nigba to n ba AWIKONKO soro so pe ko lonka lawon akekoo ti odo naa ti gbe lo, atipe ki ijoba tete wa nkan se si boya ki won gba iwe ase ibi ti ileewe naa wa lowo awon to nii ni.

Igbakeji oga ileewe Paragon, Ogbeni Adekunle Oluyinka so pe aimoye milionu lawon tin a lati dari odo naa sibo miran, sugbon pabo lo n ja si nitori pe se ni odo naa dojuko ogba awon. O ni igbese si n lo lowo lori e nitori pe kii se nkan to koja agbara.

Oludasile, Ogbeni Olumide Lawrence nigba toun naa n soro so pe aheso lasan lawon eeyan n so, o ni koun too soro, ki a koko lo o wo ipo tawon akekoo naa wa nileewosan FMC to wa ni Idi Aba nibi ti won ti n gba itoju, ka si beere lowo won nipa isele naa.

Nigba toun naa n soro, komisana foro eto eko nipinle Ogun, Arabinrin Modupe Mujota so pe oun ko gbo nkankan nipa isele atipe oro naa ko kan awon rara. O so pe ajo to n ri si oro agbegbe, iyen Urban and Physical Planning loro naa kan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI