Adigunjale meji ba Olorun lalejo lojokan soso - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 10, 2017

Adigunjale meji ba Olorun lalejo lojokan soso

Bi ki baa se pe awon olopaa ko foro naa fale rara ni, iroyin ti a n ko yi ko ni a a ba maa ko nitori pe awon adigunjale towo palaba won segi, ti won si gbabe di ero orun alakeji ko ba ti pawon eni eleni lekun, ti won a si so won si kolobo aye.

Oku awon odaran naa atawon eru ti won ji gba
Gege b’AWIKONKO se gbo, ni nnkan bi aago kan oru Ojobo Tosde to koja yi ni won lawon adigundana yi da awon oko kan duro lagbegbe J4, Ogbere, opopona Ijebu-Ode, Ore si Benin ti won si gba eru awon to wa ninu awon oko naa.

Jibowu nilu Ekoo lawon eeyan naa ti wo moto Chisco ti nomba idanimo e je AAA 649 XN, ti won n lo silu Port-Harcourt ko to o di pe awon adigundana naa da moto won duro pelu ibon ti won fi fo gilaasi e, ti won si wa a wonu igbo lati sose won.

AWIKONKO gbo pe kii se awon meji ti won ku nibi isele yi nikan ni won sose lojo naa, awon meta ni won pe won, sugbon okete eniketa won ri aaye boru mo olode awon olopaa lowo, to si na papa bora.

Enikan lara awon to n koja lo, to ri won lakoko naa lo sare lo ta awon olopaa Ogbere ekun Ijebu nijoba ibile Ijebu East lolobo ki DPO, Ogbeni Adeyinka Akingbade to o lewaju awon olopaa to ku lati koju won.

Ero ibanisoro orisirisi, egbeegberun owo, aago owo lorisirisi, baagi atawon eru miran ni won gba lowo awon ero inu oko naa pelu ibon, ti won tun n fowo te won lara paapaa awon obinrin boya eru tabi owo si wa lara won.

Lara awon ero to wa ninu moto naa, Adie Donatus to b’AWIKONKO soro lago olopaa Ogbere laaro ojo naa so pe ko din ni wakati meji gbako tawon eeyan naa fi sise buruku yi, ti won gba gbogbo eru won lowo won, o ni eleyi kii sakoko won, sugbon akoko re e to maa soju oun.

O tesiwaju pe bi won se setan pelu awon ni won sawo inu igbo pelu awon eru ti won gba lowo won. Bee lo so pe esekese ti won ti dawon lona ni okan ninu won ti gba moto lowo dereba, to si waa wonu igbo lati sose yi.

Donatus so pe inu igbo nibi tisele naa ti waye lawon si wa kawon olopaa to o de, lesekese ti won gbo pe awon adigunjale naa ti sawo igbo ni won ti tele won. okunrin naa ni o seese ko je lara awon to n koja lo lo so fawon olopaa.

Ogbeni Kunle Apanisile toun naa wa nibe so pe yato si owo to je egberun lona ogbon naira ti won gba lowo oun, won tun gba aago olowo nla pelu. Esekese lo ti gba aago e.

Alukoro olopaa ipinle Ogun to lewaju awon akoroyin debi isele naa nigba to n soro so pe bo tile je pe eniketa awon odaran naa na papa bora, sugbon oun nigbagbo pe ko ni pe towo awon yoo fi ba, tawon yoo si fiya to to je e labe ofin.

Oyeyemi rawo ebe sawon osibitu to wa nijoba ibile naa pe ti won ba ri alaisan to gbe apa ota ibon wa a ba won lati toju oun, ki won fi to awon olopaa leti, ki ise won ba a le kesejari.

Yato sawon eru ti won fibon gba lowo awon ero inu oko naa, ibon orisi marun ati okada meta ni won ri lowo awon adigundana-jale naa, bee ni won tun gba egberuun lona igba naira din die.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI