Won ti sayeye ikeyin fun Oba Onipokia - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 9, 2017

Won ti sayeye ikeyin fun Oba Onipokia

Titi di bi a ti n koroyin yi lawon eeyan si n royin bi ayeye ikeyin ti won se fun Oloogbe Oba Raufu Adeole, to je Onipokia tilu Ipokia lojo Abameta Satide to lo lohun nigba tawon afenifere atawon otokulu lawujo yawo ilu Ipokia lati se eye ikeyin fun kabiyesi won to waja.

Oba to waja
AWIKONKO gbo pe ojo ketala osu kokanla odun to koja ni Oba Raufu ti dagbere faye pe o digbose ni osibitu kan to wa nilu Eko leyin aisan ojo rampe.

Bawon Oloye laarin ilu, bee naa lawon oloselu, awon gbajumo nidi ise tiata ati orin wa nilu Ipokia lojo naa lati seye ikeyin fun Kabiyesi nitori bi won se so pe ipa ti Kabiyesi ko laarin awujo paapaa lorileede Naijiria ko see gbagbe.

Lara awon oloselu atawon eeyan jankanjankan to wa nibe lojo naa ni Omoba Gboyega Nasiru Isiaka, Onarebu Abiodun Akinlade, Onarebu Adebowale Ojo, Otunba Adigun Akeem, Oloye Titus Babajide, Sola Olaniyan, Yomi Fash Lanso.

Nibi ayeye ikeyin naa lawon omo bibi Ipokia ti lo anfaani lati gbe asa ati ise ilu won laruge, nigba ti won lo oniruuru ilu, ijo ati orin bii Efe, Abobajo ati Ajangbode lati fi dawon alejo laraya.

Awon olorin Fuji bii Taye Currency, Kunle Osebunmi ati Omo Akin Joshua lo dalu bole lojo naa.

Alaga eto ayeye naa, Ambassador Adesola Abolurin sapejuwe Oloogbe naa gege bi asaaju ti ipa rere to ko lawujo ko le pare titi lai nitori ife ati isokan to fi bawon araalu e lo.

Ojo keji osu keta odun 1986 ni Oba Raufu gbade gege bi Oba Ipokia, to si lo ogbon odun lori ite.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI