Won ti le awon omo Naijiria pada sile o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 20, 2017

Won ti le awon omo Naijiria pada sile o

Ijoba orileede South Afrika ti le aadorun omo orileede Naijiria pada wa sile latari orisirisi esun ti won ni won fi kan won to nii se pelu eto irinna ati igbelu, eyi ti won ni o n pa orileede naa lara lona to po.

Awon omo Naijiria

Ojo Eti Fraide to koja ni ijo agbenuso awon olopaa to wa ninu papako ofurufu tipinle Eko, Ogbeni Joseph Alabi jeri soro naa pe looto ni, atipe ni nnkan bi aago meta aabo ojo Eti Fraide naa ni oko ofurufu won bale, to si je pe okunrin ni gbogbo won.

O so pe oko ofurufu orileede South Afrika ti nomba e je BBB712 lo gbe won de lati ilu Johannesburg. Bee lo so pe opo ninu won ni won ko niwe igbelu to je ojulowo, ayederu iwe ni won n lo.

Bi e o ba gbagbe, ojo kejidinlogbon osu keji odun yi ni ijoba orileede South Afrika ti koko le awon omo orileede Naijiria metadinlogorun wa sile fun esun olokan-o-jokan ti won fi kan won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI