Won ko tii gbe oku Moji Olaiye de lati Canada o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 23, 2017

Won ko tii gbe oku Moji Olaiye de lati Canada o

Bo tile je pe iroyin to n lo kaakiri ori ero ayelujara ni pe won ti gbe oku gbajumo osere tiata nni, Moji Olaiya de lati Canada to ku si, sugbon awon to sunmo ebi oloogbe naa ti so pe aheso lasan ni, atipe iro to jina si ooto loro naa.

Ayederu foto ti won n gbe kaakiri
Nnkan to faa ni pe bi Asiwaju Bola Ahmed Tinubu se so pe oun setan lati sagbateru bi won yoo se gbe oku naa pada si Naijiria lati sin in lojo ti igbimo isinku ti won yan lo ki Asiwaju nile lati foro naa to leti.
 
Nibe ni Asiwaju Tinubu ti seleri wipe oun yoo na gbogbo owo to ba ye lati fi gbe oku naa wa sile, ki won si sin bo ti to ati bo ti ye nilana Musulumi. Ni bayii, AWIKONKO gbo pe won ko tii gbe oku naa de titi di asiko ti a fi n koroyin yi.

Opo lo n woye wipe se iroyin iku Moji Olaiya nikan lo wa nilu ti IROYIN AWIKONKO ko ri nnkan miran so mo, sugbon oro ko ri bee nitori pe gege bi e ti mo pe awa maa n se iwadi to jinle tawon oloyinbo n pe ni Investigative Journalism.


Fayose loun ko ri enikeni lati wa tufo iku Moji foun

Moji
Iroyin to n lo nigboro tele ni wipe ijoba ipinle Ekiti labe Gomina Ayodele Fayose ti so pe oun yoo dide iranlowo llati sagbateru bi yoo se gbe oku Moji Olaiya pada sorileede yi, sugbon Gomina Fayose ti so pe iron la patapata to jina si ooto ni.

Gomina Fayose ni kawon to n gbe iroyin naa kaakiri so ibi toun ti so o ati akoko toun menuba oro naa, nitori pe oun ko Moji Olaiya ri, atipe oun ko mo boya omo ipinle toun je Gomina fun lo n se.

Yomi Fash-Lanso si ti lo anfaani ero ayelujara Instagram so fawon omo Naijiria pe ki won dekun lati maa bu enu ate lu Gomina ipinle Ekiti, Ayodele Fayose nitori pe Moji ko fibi Kankan yato sawon eeyan to ku to n ku silu oyinbo, nitori naa, ki won panumo latari oro abuku ti won n so ranse si Gomina naa.

Gege bi akowe ipolongo fun igbimo isinku Moji Olaiya, Ogbeni Yomi Fabiyi se so sori ero alatagba Instagram, o so pe awon igbimo naa ti lo sabewo si eni to je gege bi baba isale egbe osere TAMPAN ti Moji je okan lara won, Asiwaju Tinubu lati foro iku Moji too leti lojo kokanlelogun osu yi.

Yomi so pe Asiwaju bawon kedun lori iku eeyan naa, o si seleri pe oun yoo san owo oko ofurufu ti yoo gbe oku Moji wa sile lati sin in.

Lara awon igbimo ti won yan naa ni Omo Moji Olaiya, Adunola; Yomi funra e atawon egbon Moji okunrin meji, awon naa ni won lo.

Nkan mokanla ti e mo nipa iku Moji Olaiya
*     Won ni leyin odun meji gbako ti aburo Moji Olaiya, iyen Abidemi Olaiya ku, loun naa dero orun alakeji. Ojo kerin osu karun odun 2015 ni a gbo pe Abidemi ku leyin aisan rampe ti won loo ran nirin aremabo.

*      Oyun osu mefa lomo ti Moji Olaiya bi.

*      Ise abe ni won se fun lasiko to fee bimo tuntun naa.

*      Ogbe inu (Ulcer) wa lara Moji ko too sise abe, eyi lo si pelu nnkan to se akoba fun aisan to wole sii lara leyin to bimo tan.

*      Leyin ti ara e ya die, lawon dokita ni ko maa lo sile, sugbon ko to ose meji ki wahala min in too tun de sii lara.

*     Ojo Aje Monde to koja yi ni Moji Olaiya se isomoloruko omo e ni gbongan Thistletwon lagbegbe Albion/Islington.

*      Pofupoofu (Puff-Puff) ati oti elerindodo ni won fi se isomoloruko.

*      Ilu Abuja ni oko ti Moji bimo fun n gbe nitori pe ibe lo ti n sise.

*      Nitori saare (burial ground) ni Adunoluwa ko se fi ki won sin Moji Olaiya silu Canada. O ni oun ko le ni anfaani lati maa lo yoju si saare mama oun lasiko to ba wu oun. 

*      Odun to koja ni won fi Moji Olaiya je amubasado (Ambassador) l’Ekiti nibi ayeye odun Ekiti (Ekiti State Festival).

*     Moji Olaiya lo gba Bisi Ibidapo Obe, iyen Bisi Omologbalogba kuro ninu itiju itagbangba nitori oyun to ni fun Senato Dino Melaye, paapaa nigba ti Lola Alao gbe oro naa pari.

Opo awon agba osere tiata ni won ti n lo anfaani ero ayelujara Instagram lati fi oro ibanikedun won sowo sawon ebi Moji Olaiya, lara won ni Bisi Omologbalogba, Yinka Quadri, Femi Branch to so pe Moji lo da aso asiri boun lodo Anti Fali Werepe; Funke Adesiyan, Sunday Esan to je oludasile Okiki Films, Yomi Fash-Lanso atawon min in.

Faithia Balogun-Williams, eni to lo opo wakati ninu yara pelu Mama Moji nigba to n soro leyin to bawon osere egbe e toku bii Bimbo Thomas, Foluke Daramola, Yomi Fabiyi, Kemi Afolabi, Bisi Obe atawon mi in soro so pe ibanuje nla ni iroyin iku Moji je fawon toripe ko seni to lero e ti tele. Faithia loun ko le soro pupo nitori ara oun ko tii lele daadaa.

Lara awon to ko oro sinu iwe ibanikedun ti won gbe sile Moji ni agba osere Fausat Balogun, Madam Saje to so pe oun ko mo nkan toun ti e le so.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI