Bo
se je pe opo awon eeyan lo n so orisirisi oro nipa iku to pa gbajumo
oserebinrin Moji Olaiya to ku l’Ojobo Tosde to koja yi ni nnkan bi aago meta
oru ni Osibitu Humber River to wa ladugbo Keele ni Wilson Avenue, Toronto nilu
Canada.
Moji Olaiya |
Gege
bi e ti mo pe IROYIN AWIKONKO kii se iwe iroyin ori ero ayelujara to n gbe
ayederu iroyin jade, nitori pe awa kii figba kan bo okan ninu, a so loju oloro
ni IROYIN AWIKONKO je laarin awon iwe iroyin toku, kii se awa, Olorun Oba ni.
Ohun
ti a gbo nipa iku Moji Olaiya ni pe kii soju lasan, o lowo aye ninu nitori pe
ko si nkan to se e ko too ku iku ojiji lojo naa. Won ni o si bawon eeyan soro
ni nnkan bi wakati meji ki olojo too de.
Bi
e ba tun n wa eni to sunmo Moji Olaiya julo, yato si Bisi Ibidapo Obe, iyen
Omologbalogba, Arabinrin kan ti won pe oruko e ni Keji lo tun sunmo ju bi
isan-orun nitori oun lo maa n ran Moji lowo ninu ile, paapaa to n setoju mama e
ti ko ba ti si nile.
Moji
ko too ku la gbo pe kii foro pamo fun Arabinrin Keji, won si mo irin ajo ara
won.
Nigba
to n soro lori iku to pa Moji, Arabinrin Keji so pe iku naa lowo aye ninu
nitori igbagbo oun ni pe kii soju lasan. O lawon eeyan le maa so nnkan to ba wu
won, sugbon nnkan to da oun loju nipe ise aye ni.
O
ni oun loun tun sunmo Moji ju atipe o ku ojo meta ko ku lo ti n pe oun wipe oun
ko mo bi ara se n se oun, toun si gba lawon amoran kan.
“Kogbokogbo
lomo ti Moji bi nitori pe akosile oyun e so pe inu osu karun yi lo ye ko bimo
naa, to si je pe osu meji seyin lo ti bi. Nnkan to faa ni pe ipo ti won lomo
naa wa ko dara, ti ko ba si tete bi, o seese ko ku sinu, nnkan to je ki won
tete fi ise abe gbe omo naa jade niyen.
“Aisan
yi dide leyin to bimo naa tan, toripe ojoojumo lo maa n so pe oun ko gbadun ara
oun. Ni nnkan bi aago mewa ale (gege bi onka ilu Canada), iyen laago meta oru
tiwa nibi, eje Moji bere sii ru to si daku. Awon ti won jo wa ni won sare pe
oko pajawiri nile iwosan to sunmo won lati waa gbe. Inu moto naa lo dake si ki
won too dele iwosan” Arabinrin Keji soro.
Wakati
mejidinlogun ki Moji too ku lojo Tosde, nnkan to ko gbeyin sori ero ayelujara
Instagram ni pe “Eyin ore mi, Okiki app
ti wa larowoto nibi ti e ti le ni lori foonu yin. E maa jegbadun awon sinima
lati owo mi ati lati owo awon agba osere to ku lofe.” (“Hello fans, Okiki
app is now on Apple App Store. Watch movies from me and other great actors for
free.”)
Sugbon
ko too ko eyi lo ti koko gbe aworan foto ara e, to si ko nnkan mi in to fi dupe
lowo Allah lojo Tusde pe “Alliamdulilahi
fun iwo Allah, mo fi gbogbo ope fun O fun awon nnkan too ti se. Kii se agbara
mi bikose oore ofe Allah. Ese fun ebun aaye. Ope mi lowo eyin ore mi, ebi mi
ateyin ololufe mi fun igbarukuti ati adura yin. Mo nife yin pupo.” (“Alliamdulilahi
to you Allah I give all the glory for all you have done. I will forever praise
and worship you. It’s not by power but the Grace of Allah. Thank you for the
gift of life. Thanks also to all my friends and family my fans for your
supports and prayers. Love you all.”)
Adunoluwa Ajokeade Farombi, omo Moji |
Adunoluwa
so pe oun ko mura sile nipa iku iya oun, ibanuje ati edun okan nla lo je foun.
O so pe oun ko le gbagbe mama oun toun naa maa fi ku nitori bo se maa n toju
oun. O ni ko si nnkan toun fe ti mama oun kii se foun lasiko toun ba ti fe e
si.
No comments:
Post a Comment