Ohun
tawon eeyan si n so nigboro bayi ni ti airi ounje je nibi iranti Gbenga Adeboye
ati Toba Opaleye ti egbe sorosoro Freelance and Independent Broadcasters’ Association
of Nigeria, FIBAN eka tipinle Ogun sagbateru e logbon ojo osu kerin to koja yi
ni gbongan H3 to wa ni Oke-Mosan nilu Abeokuta.
Arewa lakoko to n ko ounje |
Bo
tile je pe AWIKONKO gbo pe eeyan, iyen awon araalu to fi die din ni oodunrun
(300) lawon to ra aso opa-mefa ti won ta ni egberun meta aabo naira, to je gege
bii tikeeti feni to ba fe wole sinu gbongan ti won lo lojo naa, sugbon sibe
ironu airi ounje je lo gbe opo awon to ra aso kuro nibe.
Oun ti a gbo nipe ko too di pe won bere sii pin ounje ni gbojumo obinrin
sorosoro ori redio to sese n dide bo nni, Adebisi Oseni tawon ololufe e mo si
Arewa ti lo n gba ounje, to si n fun awon ti e to wa, to si tun gbe pamo fawon
ti won ko ri aaye wa.
Awon to n so nibi
to ti n tete gbe ounje naa pamo ko ma baa tan lai je pe o ti te awon eeyan e lorun ni won ti ya foto e ti ko si mo, bo tile je pe won ni
se lomobinrin naa ro pe ere ni won n fi kamera ti won fi ya se, lai mo pe ibi ti won fe gba yo si yato si ero okan e.
Lara
awon to wa nibi ti Arewa ti n ko ounje naa pamo sugbon ti won ko fura ni Olumide
Awolowo, Ayinla Egba, Tajudeen Saheed topo mo si Oloriire ati Bisi to je akowe
fun alaga Alawiye toun ta awon kaseeti tawon oloogbe mejeeji yi ti sile ki won
too ku fawon eeyan.
Eni
to ba ri Adebisi ti won n pe ni Arewa yi, ko so fun un pe asiri e ti tu si
AWIKONKO lowo o, ko si si n n kan to le so pe ki AWIKONKO ma gbe iroyin naa
jade sita kawon eeyan ti won kigbe ebi kuro ni pati lojo naa pe Arewa lo faa ti
won ko fi ri ounje je.
Adebisi Arewa |
Sugbon
ohun tawon kan n so fawon to si n kigbe airi ounje je lojo naa ni pe se
won ko jeun ri ni, abi ki wa ni wahala won gan an to je pe oro ounje nikan ni
won n tenumo, ti won ko ri ti ooru to fe pawon eeyan sinu gbongan lojo naa ro.
E fi Adebisi Arewa sile ko jaye ori e, nitori pe idunnu to subu lu ayo e, iyen ti ojo ibi e lo wa lokan e. Gbongan Asa, Cultural Centre to wa ni Kuto Abeokuta ni ayeye ojo ibi naa yoo ti waye, bere lati aago mefa irole.
Bakanna
ni AWIKONKO tun wa n fi asiko yi ki Odomobinrin Adebisi Oseni Arewa fun ti
ayeye ojo ibi e to fee se ni ola ojo Aiku Sande, iyen ojo kerinla osu yi. Igba
odun, iseju aaya kan ni o. Maa tesiwaju ninu ayo ayeraye Olugbala re.
No comments:
Post a Comment