Won ni Alaga egbe FIBAN ipinle fee gbe apoti eleekeji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 9, 2017

Won ni Alaga egbe FIBAN ipinle fee gbe apoti eleekeji

Sugbon okunrin naa ni ironi
 
Orisirisi oro aheso lo ti n jade labele pe Alaga egbe sorosoro to daduro, iyen Freelance and Independent Broadcasters' Association of Nigeria, FIBAN eka tipinle Ogun, Komureedi Akinyemi Titus Olatoye, Alawiye Fediresan to sese gbe ipo sile tun fee pada dupo alaga egbe naa leekeji.

Alawiye Fediresan
Nibi ayeye eto iranti Gbenga Adeboye ati Toba Opaleye, eyi ti won tun maa n lo anfaani e lati se idanilekoo fawon eeyan ni oro yi tun ti jeyo nigba ti AWIKONKO feti ko oro naa nibi tawon kan ti n so o.

Nipa ayeye eto iranti naa ti won maa n se ni a ti gbo pe se lawon eeyan naa maa n fi oruko awon agba sorosoro to ti di oloogbe na pa owo wole sapo ara won ni, atipe to ba je apo egbe ni owo naa n wo ni, ko ba tun da, sugbon apapin ni won ni alaga atawon igbimo to n fi oselu yan jo n fi owo naa se.

Opo esun ni won fi kan alaga won, pe ijoba adase lokunrin naa n se, ti kii si yoju si ofiisi egbe naa lore-koore, ojo ipade nikan lo maa n yoju lasiko to ba wuu, won ni ofiisi e to wa ni adugbo Oke-Ilewo lo ti maa n pase egbe pelu awon ti e, tawon oloye egbe naa kii sii mo nipa e.

Bakanna ni AWIKONKO tun gbo pe Alawiye ti pari gbogbo eto lati gbe apoti eleekeji gege bi alaga fegbe naa, sugbon tawon omo egbe so pe ko seese, nitori pe awon ko gbadun isejoba e, nitori awon iwa afojudi to maa n se nigba miran, bo tile je pea won kan so pe okunrin naa ni suuru pupo, paapaa ninu egbe.

Sugbon nigba tokunrin naa n ba AWIKONKO soro, Komureedi Akinyemi Titus Olatoye, Alawiye Fediresan so pe oun ko tii le so boya oun maa tun gbegba apoti idibo miran to n bo lona ninu osu keje odun yi.

O ni pe aheso lasan ni nitori pe oun koo ti ni lero lati mo boya koun pada gbegba apoti eleekeji tabi koun feyinti gege bi alaga.

Alawiye so pe ironu boun se maa jabo ayeye eto iranti awon akoni oloogbe meji ni nni, Gbenga Adeboye ati Toba Opaleye tawon se fawon omo egbe lo wa lokan oun, kii se ti idibo to n bo lona, atipe o digba toun ba ti jabo bo ya awon jere tabi awon je gbese loun yoo to o le so nnkan to wa lokan oun sita.

Nigba to n soro lori pataki ayeye iranti naa, o ni pataki tawon fi n se e ni lati ma je ki oruko Gbenga Adeboye ati Toba Opaleye parun gege bii ipa ti won ko nigba ti won da egbe naa sile ko too dipe won jade laye.

O ni awon ko gbe eto naa kale lati maa fi pa owo sapo ara won, bi ko se pe lati maa fi mu itesiwaju ati idagbasoke ba egbe ati ise sorosoro nitori awon idanilekoo tawon n se fawon omo egbe paapaa awon araalu.

O ni ona ara oto ni ayeye todun yi gba waye nitori pe awon ko lero wipe ero yoo po to bi won se po naa, o lawon eeyan aadota le ni igba (250) lawon ta aso fun, tawon si gba gbogan to gba eeyan irinwo, sugbon kayeefi lo je bawon se rii pe gbogan naa ko gba awon alejo nitori pe ife tawon araalu ni lo je ki won po ju bawon se lero lo, nitori pe opo lo so pea won ko raaye jokoo si.

Bakanna lo tako aheso lori pe kii foro to awon oloye egbe leti, ijoba adase lo n se atipe kii jokoo si ofiisi egbe, o ni awon ti ko fe ki egbe FIBAN ni ilosiwaju lo n so isokuso kaakiri nitori pe awon gan an ni igi woroko to fe kegbe naa daru ti olorun ko sin ii fun won se.

O tesiwaju pe ko si oloye egbe to n ba owo osu, owo apo ara won lawon fi n mu ilosiwaju ba egbe naa, idi niyi toun ko gbodo fi lo maa jokoo soju kan, nitori pe ibi kan lowo toun n na sinu egbe n ba wole, toun ko si gbodo so pe oun ko nii lo sibi towo ti n wole.

O so pe awon ko le se kawon ma si ofiisi naa lojumo, toun si maa n yoju sibe lasiko to ba ye, nitori pe ise akowe egbe ni lati maa bojuto gbogbo bi nnkan ba se n lo si ni ofiisi, ti akowe si n foro to n lo nibe toun leti loorekoore.

Bee lo soro lori aseyori e gege bi Alaga egbe FIBAN, o ni lasiko toun de ni ileese redio aaladani nla meji de, to si je pe opo omo egbe sorosoro lawon rii daju pe won gba sibe lati sise, ti won si n gbowo osu. O so pe oun ko le menuba awon aseyori naa tan, nitori pe eeyan kii yin ara e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI