Ile ejo ni
won wa bayii.
Mobiyina Osofa |
Kii se pe
oro naa sese bere, won ti wa lenu e tipe sugbon ni bayii, oro naa ti kuro ni
bonkele, o si ti jade sita gbangba, awon olori ijo Sele, iyen Celestial Church
of Christ, CCC ni won ti gbe ara won lo sile ejo giga to wa ni Ikoyi niluu Eko
lori esun sisowo ijo naa basubasu, ti won ko si ni akosile gidi lori bi won se
n sowo naa.
Okan lara
omo ijo naa, to tun je okan lara igbimo agbagba BOT ninu ijo naa, Alagba John
Rotimi Omotosho topo mo si Baba Jorotom lo gbe awon agbaagba ijo naa, ninu eyi
ti Olori won patapata, Mobiyina Friday Osoffa wa ninu won peluu awon merin min
in, loo si ile ejo giga keje lojobo Tosde ose to koja, nibi ti Onidajo Chuka
Austin Obizor ti n gbejo won.
Awon yooku
ti won tun jejoo peluu Olori ijo won ni Pius Olanrewaju, Ojogbon Bola
Akinterinwa, Ogbeni Segun Aina ati Ogbeni Samson Banjo. Lara awon esun ti won
lokunrin naa fi kan won ni sisi iwe banki min in to yato si eyi tijo naa n loo,
sisowo ijo naa basubasu lai le so pe bayii lawon se n nawo naa atawon nnkan min
in. Bee ni okunrin yii tun ro ile ejo pe ko pase ki awon to fesun kan naa ye
kowo bowo ijo naa mo titi ti idajo yoo fi waye.
Baba Jorotom |
Nibi igbejo
to waye naa ni Adajo ti pase pe oun fun Alagba Samson Banjo lati wa ona ti
alaafia yoo fi joba, gege bi oro ti agbejoro won so pe igba merin otooto lawon
ti gbe igbese lati yanju oro naa laarin igun mejeeji.
O ni oun
fun won laye lati loo lo anfaani naa lati yanju e sugbon ti ko ba seese, to je
pe ofo naa ni, a je pe igbejo yoo bere ni pereu. Bakan naa lo tun so pe ki
gbogbo nnkan si wa bo se wa laarin igun mejeeji to n ja naa titi ti igbejo yoo
fi waye lojo karun osu kefa odun yii.
Bo tile je
pe ko too to akoko yii lawon ti Mobiyina Osoffa ti pe Jorotom naa lejo ni kootu
giga keta to wa ni Ikoyi nipinle Eko bakanna pe ki okunrin yii wa so bo se se
milionu mejile laadosan naira(N172 milionu), ti won lo je lara owo ti won fi n
ko Jerusalem tuntun to wa ni Imeko, eyi ti won lo wa ni ikawo e lakoko to fi je
alaga igbimo fun kiko ijo tuntun naa, sugbon se ni Onidajo Kaka to n gbejo naa
da ejo ti won pe okunrin naa nu, nitori won ni ko lese nile.
Ni bayii,
ko seni to le so pato ibi ti ejo naa n loo, nitori bi awon ti Jorotom fesun kan
se so pe awon ko jebi, ati pe kii se nnkan to bojumu lati maa gbe olori ijo loo
si kootu. Sugbon tawon ti Jerotom so pe o dawon loju pe idajo ododo yoo waye,
nitori awon mo pe inu okunkun biribiri lawon ti won fesun kan fi awon omo ijo
Sele si, ti Olorun si ti setan lati tu asiri won sita.
Jorotom atawon alagba kan ni Ketu |
Atipe Jorotom funra e ti figba kan so
pe kii se pe oun fee dupo olori ijo naa tabi pe oun n wa ipo nla ninu Sele loun
se n sagbateru lati tu asiri awon to n ba ijo naa loruko je, bi ko se pe
alaafia, isokan ati idagbasoke ijo Sele loun n wa, atipe ki ileri Olorun fun
ijo naa le wa si imu se nipa fifo aye mo loun fe ko wa si imuse.
O soro naa lojo ajinde to waye ninu ijo
Sele, eka e to wa ni Akowonjo, iyen Jerusalem Parish Cathedral, o tun so pe oun
ko le fi ejo naa sile lai je pe ile ejo da ejo naa bo se to ati bo se ye nitori
pe awon ti Baba Oshoffa ti ba oun naa loruko je pe oun kowo je.
No comments:
Post a Comment