Wale Thompson gborin tuntun jade - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 31, 2017

Wale Thompson gborin tuntun jade

Gbajumo olorin fuji nni, Ogbeni Wale Thompson topo mo si Misita Lalale Fraide ti gbe orin titun jade bayii leyin opolopo odun tokunrin naa ti korin gbeyin latari ijamba oko kan to ku die ko gbemi e.

Gege bi AWIKONKO se gbo, Chop My Life lakole orin titun ti Wale Thompson gbe jade, tawon eeyan paapaa awon ololufe e to n gbo orin naa si n kan saara sii pe orin si n be lara e gidi gan.

Ileese to n gbe orin jade ti won pe ni Godfather Music lo gbe orin naa jade, topo awon eeyan lorisirisi si ti n gbe osuba kare fookunrin naa pe ise lo se.

Bi e o ba gbagbe, Lalale Fraide lorin to gbe Wale Thompson sita faraye tawon ojogbon nigba naa si so pe oun loba awon olorin juju latari awon alujo ati takasufe to fi kun un.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI