Wahala de; Won ni Alatan na ika abuku si Alake - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 9, 2017

Wahala de; Won ni Alatan na ika abuku si Alake

Iroyin kan to n lo kaakiri igboro ipinle Ogun bayii ni ti wahala kan ti won ni o wa nilu Atan nijoba ibile Ado-Odo Ota ipinle Ogun, nigba ti won so pe Oba Solomon Adebiyi Isiyemi to je Alatan tilu Atan lo agbara toni lati fi yo kilanko Alake tile Egba, Oba Adedotun Aremu Gbadebo kuro ninu oro Atan.

Alake

Gege bi AWIKONKO se gbo, oro ile kan ni won ni Oloye Alimi Daada ati Lamidi Sobola Adejare jo n fa to si je pe Alake lo n gbiyanju lati yanju wahala naa laarin awon mejeeji ki o ma baa si wahala tabi ikunsinu laarin awon eeyan Atan.

Oro ile naa gege bi atejade ti ajo kan ti won pe ni Equalrights Attorneys fi ranse sijoba ipinle Ogun lati tete boju wo oro naa ko too pe ju, eyi ti eda te wa lowo lose to koja se so, ni won so pe ko kan Oba Isiyemi rara, sugbon o lo ipo naa lati fi so pe oun ko nii gba ki eni ti kii se omo Atan wa maa da si nnkan ti ko kan, eyi to si ti gbe oro naa lo sile ejo wipe ki ileejo da Oba Gbadebo lowo ko lati maa da si oro Atan.

Ejo naa to je OT/14/2017 ni won ni Oba Isiyemi ti bura  to si lo roba onte e lati fi bu owo lu iwe ase naa lati fi so pe Alake ko lase lati pase nilu Atan nitori pe kii se agbegbe naa lo joba si. Won ni iwa ti Alatan hu yi ti da opolopo wahala ati awuyewuye sile leyi to le je ki alaafia salo fun ilu Atan bi won ko ba tete mura si.

Alatan
Abala kerin si ikefa ati iketala ninu iwe esun ti won ni Alatan ko si ileejo lo bayii pe “Nipa oye ati imo ti mo ni je ko di mimo pe gbogbo abule ati igberiko to wa ni isakoso mi ko si labe isakoso Alake tile Egba. O je eri to daju pelu oye mi pe Olota tilu Ota nikan lo lase lori Alatan, gbogbo awon abule to si yi Atan ka pelu awon Baale lo wa labe isakoso mi. O je eri to daju fun mi pe ko si omo Egba Kankan tabi omo Owu Kankan tabi enikan to n je Olatunji Abiodun Oluyomi je Baale tabi Oba ni Atan Ota, nijoba ibile Ado-Odo Ota ipinle Ogun titi doni.”

O tesiwaju pe ni abala ketala pe “Gege bi eri aridaju pelu liana ati eto isese, Olota tilu Ota nikan lo lase lori gbogbo abule ati igberiko to yi ijoba ibile Ado-Odo Ota ka, to fi mo ile Awori, kii se Alake tile Egba rara.”

AWIKONKO gbo pe gege bi ilana ofin to n ri si oro oye jije nipinle Ogun ti odun 2004 se so, won ni Oba alaye merin lo wa nipinle Ogun, awon naa ni Alake tile Egba, Awujale tile Ijebu, Akarigbo tile Remo ati Olu Ilaro. Awon mereerin ni won si ni osise mewa, Oba Olota lo gbeyin ninu awon osise yi ti ko si lase lati da nkankan se lai gbase lowo Alake.

Ohun ti a gbo nipe Alake tile Egba, iyen Oba Gbadebo lo fa Oba Isiyemi kale fun Olota, Oba Moshood Alani Oyede, iyen Oba Olota lati fi je Alatan pelu ileri wipe Oba naa yoo se daadaa bi won ba yan an sipo gege bi Alatan tilu Atan Ota.

Bo tile je pe won ni ijoba ipinle Ogun ko tii soro lori oro naa, sugbon gbogbo igbese lati ba Oba Solomon Isiyemi soro lo jasi pabo titi di bi a ti n ko iroyin yi lowo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI