Waala ijo CCC ko tii pari o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 9, 2017

Waala ijo CCC ko tii pari o

Ojobo Tosde ose to koja ni  okan lara igbimo agbaagba ijo iyen BOT ninu ijo Sele,Alagba John Rotimi Omotoso gbe Pasito ijo naa, to tun je olori, Alagba Emmanuel Mobiyina Osofa atawon merin in min tawon naa dipo pataki mu loo sile ejo giga ijoba apapo keje,to wa ni Ikoyi lori esun pe won sowo ijo naa basubasu, bee ni won tun loo si akaunti min in to yato si eyi ti won lo fun ijo naa.

Awon tokunrin naa tun pe lejo ni Ogbeni Pius Olanrewaju,Bola Akinterinwa,Samson Olatunde Banjo ati Ogbeni Segun Aina. Ninu iwe ipejo ti nomba e je FHC/L/CS/484/2017 eyi ti won ni onidajo Chuka Austine Obiozor n gbo ejo naa.

Bo tile je pe onidajo to n gbejo naa ti sun igbejo lori awon esun ti okunrin naa fi kan Olori ijo Sele atawon eeyan e yii dojo karun un osu kefa odun, amo ki ohun gbogbo si wa bo se wa.

AWIKONKO gbo pe kii se pe wahala naa sese bere laaarin awon igun mejeeji ti wonm n ja naa, a gbo pe igba kan ti okunrin ti won pe ni Omotoso ti koko ko leta sawon olopaa to n gbo esun lilu jibiti eyi to wa ni Milverton ni Eko lori awon esun yii.

Loju ese la gbo pe awon olopaa ti gbe igbese ti won si ranse pe Osofa atawon yooku, bo tile je pe won ni Osofa ko yoju sugbon awon yooku yoju, leyin ti won gboro lenu won tan ni won ni ki won maa loop e iwadii si n tesiwaju.

Sugbon ko tun pe ni awon olopaa Panti naa tun ranse sawon eeyan naa ti won si so pe lati Abuja ni ase ti w ape won gbodo we ara won mo lori bi won se ni won nawo ijo lona aito, ti won so awon omo ijo sinu okunkun.A  gbo pe leyin tawon yen tun foro wa won lenu wo peluu awon iwe eri ti won ko dani, ni won tun ni ki won maa loo sile pe iwadii tun tesiwaju.

A fi bo se di ojooru Wedse, ojo kerindinlogbon osu to koja, tawon ti Osofa atawon eeyan e yii pe okunrin to n pe won lejoo, to folopaa le won kaakiri lejo si ile ejo giga tijoba apapo keta to wa ni Ikoyi ti nomba ipejo e je FHC/L/CS/409/17 pe okunrin naa iyen Omotoso gan lejoo lati je won ni ko wa salaye lori bo se na milionu le mejilaadosan naira iyen 172million, owo ti won ni ki won fi ko soosi nla ni Imeko,sugbon to ko ti see fawon igbimo ti won yan.

Bo tile je pe Onidajo Kaka to n gbejo naa da ejo naa nu,to ni ko lese naa nile,bi won si se pari e ni won bere eyin ti o pe Osofa atawon eeyan e naa.

AWIKONKO gbo pe ko to dip e oro naa dii pe won n gbe ara won loo ile ejo ni won ti gbe igbese lati rii pe won yanju e labele, sugbon iyalenu lo je pe bawon ti Osofa se fesun kana won ti Omotoso pea won ni ko gba ipade alaafia laye bee lawon tohun naa gan ni won fee oro naa loju sii.
Oniroyin wa tiraka lati gbo tenu awon ti Omotoso fesun kan, ohun tawon yen so ni pe niwongba toro naa ti w anile ejo, ko si nnkan tawon fee so mo.

Sugbon enikan to ba oniroyin wa soro so pe aseju Omotoso naa ti poju, nitori awon ko mo nnkan tawon fee tun se mo lori oro yii, won ni gbogbo esun to fi kan Osofa atawon eeyan yii ko lese nile,niwongba to ti gbe awon dele ejo, gbogbo eri maa jade.

Amosa, Omotoso ni kii se pe oun fee je Pasito tabi gba ipo mo Osofa lowo sugbon ohun fee je kaswon eeyan mo bawon eeyan naa se n pawo ijo si apo ara won, ti won si so awon eeyan sinu okunkun.

Peluu gbogbo bi nnkan se n look o ti senikan ninu awon igun mejeeji to le so ibi ti ejo naa yoo fidi si, bee ni ko ti seni to le so pe oun jawe olubori niwogba ti igbejo n loo lowo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI