Tegbon taburo ja ileese Coca-Cola Ota lole ogbon milionu naira - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 23, 2017

Tegbon taburo ja ileese Coca-Cola Ota lole ogbon milionu naira

Ileese olopaa ipinle Ogun ti rowo to egbon ataburo kan ti won je omo baba kanna ti won fesun kan pe won lo fo ileese Coca-Cola to wa ni Ota ipinle Ogun lojo Aje Monde ose to koja yi.

Kii se tegbon taburo yi nikan lowo olopaa te ni nnkan bi aago mefa aaro, awon merin min in naa wa lara awon towo te, ti won si ti wa lakolo awon olopaa bayii nibi ti won ti n ka boroboro bi eye orofo. Agbegbe Alishiba, Sango Ota lowo ti te won.

Ikechukwu Onwe, eni ogbon odun; Chukwunma Onwe, eni odun marundinlogoji; Onyebuchi Muruako, eni odun metadinlogbon; Obiora Onyemuazu, eni odun mokandinlaadota; Chidi Monday, eni odun merinlelogbon; ati Mutiu Olodigbo ti won ni ogoji odun lojo ori e.

AWIKONKO gbo pe Monday, to lewaju awon mefa yi ti na papa bora bo tile je pe awon olopaa si n wa tosan toru. Opo batiri moto nla; awon enjiini tirela; ero afefe ti won fi n fo ile; awon radiato lorisirisi ati apefon olokan-o-jokan towo won to ogbon milionu naira ni won ni won ji ko ninu yara nla ti won n ko nnkan si.

Iroyin to te AWIKONKO leti ni pe awon eso ojulalakanfinsori, Fijilante, iyen Vigilante Group of Nigeria (VGN) to n so agbegbe naa lo ri awon odaran yi laaro ana, lakoko ti won n ko awon eru ti won ji naa bo sile ninu moto niwaju ita ile Monde, ti won si tete fura pe won kii se osise ileese Coca-Cola.

Lesekese ni won ti lo koju won, ti won si beere pe nibo ni won ti ri awon eru naa, esi ti won fun won lo je ki asiri won tu sita, nigba ti won tun so pe se leni to si tirela naa n gbon lakoko naa, to si je ki won ri eri aridaju pe se ni won lo o ji awon eru naa.

Nibe ni won ti te awon olopaa Onipaanu laago lati waa ko won. ko too dipe owo bawon, AWIKONKO gbo pe awon odaran yi ti bawon Fijilante naa woya ija repete.

Oga olopaa Onipaanu la gbo pe o lewaju awon olopaa to lo ko won, ibe naa ni won ti gba tirela atawon eru ti won jigbe lowo won, won ni won ko je ki won ri aaye lati gbe e jade sita nigba tasiri won tu.

Eni to gbe oro naa si AWIKONKO leti so pe “Nigba ti won n ja awon eru ti won ji ko naa bo sile ninu tirela nile Monday lowo te won. Monday ni olori won sugbon ko tele won lo sibi ti won ti lo jale. Awako tirela naa, Olodigbo so pe se ni won gba oun bo tile je pe oun ko mo ero okan won ati ipinu ti won ni afigba ti won de ibi ti won ti lo ji eru naa ko.

“Ohun to so nipe won fi ipa mu oun lati bawon ko awon eru naa ni, atipe nigba ti won debi ti won ti n ja eru naa sile loun pariwo le won lori kawon Fijilante too de ba won.”

Awon odaran to ku la gbo pe won ko tii jewo fawon olopaa titi di bi a ti n koroyin yi lowo, sugbon agbenuso awon olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi ti jeri soro naa pe looto ni.

Abimbola so pe komisana awon ti pase pe ki won ko awon odaran naa lo si ogba awon olopaa esin-o-koku lati tesiwaju ninu iwadi lori awon odaran naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI