Skeledy |
Ohun ti a
gbo nipe Kasnaty lo n je oruko naa tele, iyen Skeledy Gbangba, to si ti fi
oruko naa sile lati nnkan bi odun meta seyin ko too di pe odomokunrin Adedeji
yi gba oruko naa.
Sugbon
iyalenu lo je lori bawon kan se n soro pe nibo lo ti wa, to fi je pe oun lo fee
maa je oruko naa, to si fe maa se bi ti Kasnaty.
“Mo fee dabi lagbaja ko see se”
lohun tawon kan n so nipa boi yi, bee ni won ni igberaga e ti n fee maa poju ti
Kasnaty lo, sugbon eni to ba ri Adedeji yoo mo pe onirele eeyan ni, ko si seni
ti ko le pe ni ‘oga mi’.
Adedeji
nigba to n fesi soro naa, o so pe nigba toun jokoo lati wo oruko inagije toun
fee maa lo lati le je kawon eeyan tete mo oun, o so pe ko soruko meji to wa
soun lokan bi ko se Skeledy naa, sugbon loju ese loun pe Kasnaty lati fi too
leti, to si so pe ko si nnkan to buru nibe, latigba naa loun sit i n je oruko
naa.
Kasnaty
nigba to n soro lori oro naa lo so pe ko si nnkan to kan enibodi nipa oruko ti
enikeni ba fee je, atipe nipa oruko naa, oun ko lo oruko naa mo tipetipe. O ni
wipe Adedeji n je oruko naa, iwuri lo je foun nitori pe oun tun ri eni to n je
oruko toun fi sile.
Bakanna lo
so pe, ki Adedeji maa tesiwaju lati je oruko naa nitoripe ko da ilosiwaju oun
duro, ko si so pe kawon onibara oun ma wa oun wa polowo oja lodo oun, onikaluku
lo ni ololufe tie.
No comments:
Post a Comment