Owo
olopaa ipinle Ogun ti ba odomokunrin ogun odun kan, Segun Olaseni ti won fesun
kan pe o fipa ba omokekere odun mesan sun laduugbo Eniola, New Life Estate
nijoba ibile Ota, ipinle naa.
Segun Olaseni |
Gege
bi AWIKONKO se gbo, ojo Aiku Sande to koja yi ni won so pe Segun loo ki awon
obi omo naa nile, sugbon bawon obi naa se bo sita, ni won so pe Seugbon tan omo
naa wo yara baba e, to fi bo pata e.
Die
lo ku ki Segun da ato e somo naa labe ki baba e, Ogbeni Adepoju Akinyemi too
wole kaa, to si ko abara ati ese bo Segun wipe o fipa ba omo oun sun. Omo naa
la gbo pe Segun fowo boo lenu nigba to fe maa sunkun lakoko to n ko ibasun fomo
naa karakara ko too di pe baba omo yi wole.
Ariwo
ti Adepoju pa pe kawon araadugbo gba ohun lo mu kawon eeyan sare wole pe ki lo
n sele, sugbon se ni Segun n wo pakopako nigba tawon eeyan ri pata lasan nidi
e, to si fowo bo nkan omokunrin e.
E
pami sile, e ma pami sita lebe ti won ni Segun n be awon to rii, sugbon awon
kan lo so pe ki baba omo naa lo foro yi to awon olopaa leti, ko ma se se idajo
lowo ara e, ko ma baa jebi ofin ijoba.
Tesan
olopaa to wa ni Sango Ota ni Adepoju sare gbe okada lo, to si kilo fawon to fa
Segun le lowo pe won ko gbodo je ko lo. Nigba to de be, to salaye fawon olopaa,
loju ese ni DPO Akinsola Ogunwa ti gbera, to si ko sinu oko pelu awon olopaa
lati lo mu Segun.
Segun re o |
Boroboro
ni won so pe Segun nka nigba to de tesan olopaa, se lo so fun won pe ki won se
oun jeje, oun a jewo gbogbo ara toun ti n fomo naa da lateyin wa. O ni adugbo lawon
jo n gbe, oun ko si le se lati ma lo sile won lojumo.
O
ni ko sigba toun lo sile won ti won kii se oun daadaa, nitori se lawon obi omo
naa mu oun gege bi omo, ti won si maa n ran oun nise. O ni won kii foro sabe
ahon so foun gege bi owo ti won fi mu oun.
AWIKONKO
gbo pe Segun tun so ninu oro e pe kii se akoko toun maa koko ba omo naa sun
niyen, atipe tawon obi e ko ba ti si nile loun maa n se kini fun. O so pe ise
esu ni tori pe oun ko maa n mo bi nnkan naa se n sele. O ni oun maa n fipa mu
omo naa ni, oun si ti kilo fun un pe ko gbodo so.
Nigba
to n jeri soro naa, alukoro olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi so pe
looto ni atipe komisana awon, Ahmed Iliyasu ti gbo soro naa, o si ti ti bu enu
ate lu iwa ibaje ti Segun hu naa.
Iliyasu
ti wa pase pe ki won gbe Segun lo sodo ajo olopaa to n ri si lilo omo nilokulo
ati fifi omo se owo eru, iyen Anti Human Trafficking and Child Labour Unit of
the State Criminal Investigation and Intelligence Department (SCIID) lati
tesiwaju ninu ise iwadi boya awon omo adugbo ti Segun tun se iru nkan be fun si
wa.
O
wa gbawon obi lamoran ki won rii daju pe won n bojuto awon omo won ki won si mo
iru eni ti won n fi omo won ti, nitori pe ko seni to see fokan tan mo lasiko
yi.
AWIKONKO
gbo pe Segun ko ni pee foju bale ejo lori oro naa lati gba idajo to to si.
No comments:
Post a Comment