Lakoko to n na owo |
Bo se n ki
owo bo apo otun, bee lo n towo bo apo osi to si n bu apekanuko owo jade, to n
na fawon to ba duro niwaju e loju agbo ti Taye Currency ti sere.
Sugbon kii
se pe okunrin naa muti yo, bi ko se pe inu e lodun ju, nitori pe odun asa ni
won se lojo naa, idi niyii to fi gbe osuba kare fun eni to sagbateru eto naa pe
ise lo se.
Won ni bi
e ba pe Omodo-Agba si pati, ko ni yoju, kii se ti igberaga, bi ko se pe gege bi
eto ise aye to n se, o lawon ode ti iru won gbodo maa lo. Won ni bi e ba pe e
pe aburu kan sele to seni ni kayeefi, laarin iseju bii melo kan ti e pe, kawon
eeyan miran too de be, Omodo-Agba le maa koko ri nitori pe ibi tawon ti n
gbajumo niyen.
Nigba toun
funra e n soro lori idi ti ko fi maa n fi gbogbo enu soro tan lori awon isele
to maa n na sita lori afefe, o ni nigba toun si maa n tele oga oun Kolawole
Olawuyi lo seto, nibi toun ba jokoo si lowo eeyin lawon eeyan ti maa n so
orisirisi pe Kola Olawuyi ko mo bi won se n senu po to ba n soro. O loun ko fi
iku e yo, sugbon oun gbodo maa fi ogbon se nkan toun ba n se.
Bee lo
soro lori iwa awon eeyan, paapaa awon ololufee redio, o so pe eni tawon eeyan
ba ri ni won maa n kan saara si nitori pe leyin toun kuro lori eto Teledalase
toun n se nileese redio ipinle Ogun, iyen OGBC ti Ogbeni Makinde Fasunle si gba
ise naa, fun bii ose meta lawon eeyan fi pe oun pe ko seni to le seto naa bi
oun, sugbon nigba to ya, won ko pe oun mo, Fasunle ni won tun n gbosuba fun.
No comments:
Post a Comment