Se looto ni Ooni Ife atiyawo e sun lo ni pati? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 16, 2017

Se looto ni Ooni Ife atiyawo e sun lo ni pati?

Iroyin to n lo kaakiri ori ero ayelujara bayii ni ti foto kan ti won n gbe kiri ni ti Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi ati Olori e, Wuraola nibi ti won ti n toogbe nibi eto ayeye kan to waye laipe yii.

Oba Ogunwusi ati Olori Wuraola
Bo tile je pe ohun tawon kan n so lori foto naa nipe kawon to n polongo foto naa kiri ki won simedo, ki won sora won, nitori o tun seese kawon alale dide ogun siru awon eeyan bee, bi won ko ba sora, nigba ti won tun fi ti Oba Eleko, iyen Oba Rilwan Akinolu sapejuwe.

Ninu nnkan ti AWIKONKO ri gbo nipe, won ni o seese ko je pea won mejeeji ti se aisun, eyi to si ye fun won lati sinmi daadaa ki won too wa sibi eto yi lojo naa.

Bee lawon kan so pe awon ti won ko nise ni won n raaye lati maa fonrere foto naa kaakiri. Tawon kan si n so pe ara kii se okuta.


Bakanna lawon kan tun so pe o seese ko je pe awon to tuko eto naa ni won je ki nkan su awon eeyan, nitori pe kii se gbogbo MC tabi olootu eto lo mo nipa bi a se n dawon eeyan laraya.

Sugbon sa o, titi di asiko ti a fi n ko iroyin yi, AWIKONKO ko tii ri gbo nipa ibi tawon onifoto ti ya Ooni ati Olori e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI