Lojoru
Wesde ose to koja ni egbe Fuji Musician Association of Naijiria, FUMAN, eka
tipinle Ogun se ibura fawon oloye titun fegbe naa ni gbogan to wa ninu ogba
Olumo, ladugbo Ikija Abeokuta.
Paseda ati Malaika lakoko ti won pade |
Sugbon
nigba ti Otunba Paseda n soro lo ti so pe ninu awon nnkan ti a fi n gbe asa ati
ise laruge nile Yoruba, orin kiko, paapaa orin Fuji je okan pataki, ti ko si
see fowo yepere mu, nitori e loun se feran Fuji, toun ko le se lati ma
gbo.
Leyin ti
Paseda n kadi oro e nile, o so pe bi oun ba wole gege bi Gomina ipinle Ogun
lodun 2019, ki won wa lati wa ran oun leti wipe oun seleri ile nla fun won, eyi
ti won yoo maa lo lati maa sere, tawon ololufee won yoo si wa maa woran won.
Bee lo tun fun won ni egberun lona igba le ni aadota naira, iyen 250,000naira.
Paseda ati Malaika leyin ti won pade |
Bo se ku
die ki Paseda de odo Malaika, ni won so fun un pe Paseda lo n bo yen, ko lo
pade e, sugbon n kan to so nipe talo n je be, talo mo o ri, lati ibo, sugbon
lara awon agba egbe naa lo so pe okan lara awon oludije to n lewaju fun ipo
gomina ipinle Ogun, ko too di pe, o ni ki won je ko wa ba oun nibi toun wa.
Bo tile je
pe Paseda ko mo nnkan to n sele nitori pea won ero ti wa niwaju e, sugbon nigba
to de odo Malaika, se lo ki daadaa bi eni pe won ti mo ara ri tele, to si so pe
oun maa n gbadun awon orin e, toun naa si kii pe ose.
Awon toro
naa soju e lo so pe iwa ti Malaika hu lojo naa ku die kaato, nitori pe iwa
igberaga ni, atipe ko ye ko se be. Bakanna la tun gbo pe fun bii wakati meje ti
Malaika lo ninu ogba Olumo yi, ko fi iseju kan yoju sibi ayeye ibura fawon
oloye egbe tuntun naa, se ni won ni o da won nu bi omi isanwo.
No comments:
Post a Comment