Owo ti ba Shakiru ogbologbo ajagungbale l'Ogijo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 3, 2017

Owo ti ba Shakiru ogbologbo ajagungbale l'Ogijo

Ileese olopaa ipinle Ogun lose to koja ti rowo to okunrin kan, Shakirudeen Shittu ti won so pe ogbologbo ajagungbale ni lose to koja lagbegbe Ogijo ipinle Ogun.

Shakiru atawon nnkan ti won ka mo lowo
Gege bi AWIKONKO se gbo, won ni agbegbe Ipinyewa Phase 2, Ekoo ni Shakirudeen n gbe, to si maa n wa digungbale lowo awon eeyan to wa lagbegbe naa.

Won ni kii se pe Shakirudeen n digungbale nikan, bi ko se pe o tun maa n se ise omo onile lati gbowo lowo awon to ba ko si panpe e.

Nigba towo palaba e segi lawon toro naa soju e bere sii so orisirisi pe kii se akoko to ti n sise naa niyen, won ni o ti pe to ti n sise ibi naa.

Bakanna ni AWIKONKO tun gbo pe opo emi lo ti towo Shakirudeen bo lori oro ile nitori pe ko le se ko ma gbe ibon rin to ba ti fee lo dawon eeyan lowo ko lori ile ti won ba ti n sise.

Lojo tasiri e tu sawon olopaa lowo yii, won lo o ti gba owo to to egberun lona mejidinlaadorun (#87,600) naira lowo awon to lo hale mo, ko too dipe won sin eni naa ni gbere ipako pe ko foro naa to awon olopaa leti.

Loju ese ni won ni eni naa ti te awon olopaa laago, ti DPO Tijani Muhammad si lewaju awon olopaa to lo koju oun atawon emewa e lojo naa.

Won ni bawon olopaa se debe lawon ti Shakirudeen ko leyin ti na papa bora, sugbon toun duro pe ko si nkan tawon olopaa naa fee se foun nitori pe ile ebi oun ni.

AWIKONKO gbo pe fun bii wakati kan aabo ni won fi fa oro naa ko too dipe won sakiyesi ibon lowo e, eyi ni won loo bi awon olopaa naa ninu ti won fi wo sinu oko won, ti won si gbe e lo si tesan won.

Agbenuso fun ileese olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n jeri soro naa nijeta, iyen lojo Aiku Sande to koja yi lo ti so pe gbara ti Komisana won, Ahmed Iliyasu ti gbo lo ti pase pe ki won tete maa gbe odaran naa bo wa si Eleweran.

Abimbola ni orisirisi ibon akotamin mefa pelu ota ibon to to marundinlogorin atawon oogun abenugongo to fi n sise buruku naa ni won ri gba lowo e leyin ti won mu.

Iliyasu ti waa pase pe ki won si tesiwaju lati wadi Shakirudeen ki o baa le jewo ibi tawon elegbe e toku wa. O wa seleri pe Shakirudeen ko nii pe foju bale ejo labe ofin to tako iwa ajagungbale nipinle Ogun.

Bakanna lo tun sekilo pe kawon ajagungbale toku tete fi ipinle Ogun sile nitori pe ileese olopaa ko tii setan lati faaye sile fun iwa odaran, paapaa iwa ajagungbale.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI