Ileese olopaa ipinle
Eko ti rowo to okan lara awon ogbologbo adigunjale to n yo ipinle naa lenu.
Lanre Olowojobi ti inagije e je Pumpy, eni odun metadinlogoji to je omo bibi
Ipoti nilu Ekiti lowo te lagbegbe Mushin lopin ose to koja yi.
Lanre Pumpy |
AWIKONKO gbo pe,
lakoko tawon olopaa lo dojuko awon odaran nibi ahere won lagbegbe Akala,
Idi-Oro ati lagbegbe Fadeyi. Won lawon omo egbe Lanre ti seku pa opolopo awon
awon eeyan nipinle naa ati agbegbe e.
Lanre la gbo pe o
jewo gbogbo awon iwa odaran to ti hu seyin lago olopaa leyin towo palaba segi.
O ni ko din ni ogbon awon obinrin loun ti fipa ba sun laarin odun meta.
O lawon omoleyin oun
lo maa n fa a, nigba ti won ba wo eni ti won ba fee kawon se ni jamba, paapaa
awon obinrin wonu igbo, tawon yoo si fipa bawon sun, o lawon min in maa n daku
mo awon labe.
Bee lo tun so pe
eeyan to le ni mewa loun ti yinbon pa lagbegbe Akala ni Mushin lakoko tawon ba
n fa wahala, o so pe ko seni ti ko mo oun, ti won si maa n beru oun.
Lanre tun so siwaju
pe odun 2008 loun darapo mo awon egbe kan, toun si da egbe toun sile lodun
2010. Lawon merin lawon jo bere, sugbon tawon si ti pe mewaa bayii.
Bakan naa lo tun so
pe yato si pe awon n sise ajagungbale, tawon si n gba garaaji, o lawon tun
lawon omo to n bawon ta igbo kaakiri ipinle Eko ati agbegbe e.
No comments:
Post a Comment