Owo ni ko je ka ti pari awon ise l’Ogun – Amosun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 31, 2017

Owo ni ko je ka ti pari awon ise l’Ogun – Amosun

Gomina ipinle Ogun, Asofin agba Ibikunle Amosun ti so lojo Aje Monde to koja yi pe aisi owo to to ni ko je kawon ti pari awon akanse ise tawon dawole kaakiri origun mereerin ipinle Ogun.

Gomina Amosun
Amosun soro yi lakoko to sabewo kaakiri awon agbegbe ti ise ti n lo kaakiri ipinle Ogun lati saami ayajo ojo isejoba awaarawa to waye kaakiri orileede Naijiria lojo Aje Monde, ojo kokandinlogbon.

Nibi to tun ti lo anfaani naa saami ayeye odun kefa gege bi Gomina ipinle Ogun, nibe lo ti so pe awon ise naa le dabi eni pe ko wulo, sugbon nitori wahala ojo iwaju loun se dawole awon akanse ise naa.

O loun ko le feti sohun tawon kan n so kaakiri pe oun n sun owo ipinle Ogun nina, sugbon nnkan ti ko ye won po ju awon nkan to ye won lo nitori pe, adura ni won a si maa se nigba ti asiko ba to.

O ni logorun odun si asiko yi lawon eeyan yoo si maa kan sara si ijoba oun paapaa lori awon afara oloke toun se kaakiri ipinle Ogun.

Amosun so pe ijoba oun ti n gbiyanju lati tesiwaju ninu awon ise naa, atipe awon agbasese tawon gbe awon ise naa fun ti pada senu ise won, won si ti n ba ise lo, laipe laijina, won ko ni pe pari awon ise naa.

Bakanna lo seleri pe losu meji sigba taa wa yi loun yoo si awon afara oloke merin to ti fee pari kaakiri ipinle naa, nitori pe ise ti fee pari.

Lara awon ibi ti Amosun sabewo si ni Abeokuta, Ayetoro, Imeko-Afon, Ilara, Eggua, Oja-Odan, Ilaro, Sango-Ijoko, Ojodu, Sagamu, Ilishan, Ago-Iwoye, Ijebu-Igbo ati Ijebu-Ode.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI