Ose meje gbako ni won maa fi ti fasiti Ibadan pa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 31, 2017

Ose meje gbako ni won maa fi ti fasiti Ibadan pa

Lojo Aje Monde to koja yi igbimo ileeko Fasiti ilu Ibadan, iyen UI pase pe ohun ko fe e ri akekoo kankan ninu ogba ile eko naa, to fi mo awon ile akekoo to wa ninu ogba naa lati aago mefa irole.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ko too digba naa lawon akekoo UI ti koko da wahaala sile, eyi ti won fi fehonu han sawon oga ileeko naa latari awon iwosi ti won ni won fi n lo won, ti ko si te won lorun.

Fawon to ba mo faisti UI, yoo mo pe inu osu kefa to m bo yi lawon akekoo yoo bere idanwo won, gege bo ti se wa ninu akosile, inu osu keje ni won yoo si pari e.

Sugbon ki wahala naa ba a pa ile eko atawon osise naa lara, lo mu ki giwa ileeko naa, Ojogbon Idowu Olayinka pe ipade pajawiri sile igbimo asofin to wa ninu ogba naa lati dide igbese.

Nigba to n soro, alukoro ileeko naa, Ogbeni Olatunji Oladejo so pe ko si nkan tawon le se soro naa wipe kawon ma le won lo sile loranyan. O lawon akekoo tuntun ti won sese gba, ojo ketadinlogun osu keje lo ye ki won wole pada lati bere ise, tawon to si ti w anile eko naa tele si maa tesiwaju, sugbon ko si nkan tawon le se si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI