Kani awon osise
ileese redio ipinle Ogun, OGBC mo pe ibi ti oro naa maa ja si niyen, bo ya won
ki ba tun ti gba ona miran yo si ijoba ipinle Ogun lori iyanselodi olojo
gbogboro ti won gun le laaro oni, Ojoru Wesde.
Gomina Amosun |
Ni nnkan bi aago
marun un owuro yi ni AWIKONKO gbo pe awon osise ileese redio OGBC ti ji de
ofiisi pelu kokoro nla ti won si fi ti gbogbo enu ona aba wole sinu ileese
redio naa, eyi ti won tun so pe oga agba pata nibe ko ri aaye lati wole,
depodepo pe won yoo sise.
Gomina ipinle Ogun,
Ibikunle Amosun ti wa da awon oga agba ileese redio ati telifisan ipinle Ogun,
iyen OGBC ati OGTV duro lori iyanselodi naa. Ohun ti a gbo pe o fa idaduro yi
ko ju ti suuru tijoba so pe kawon eeyan naa ni lo, to si je pe se ni won so pe
iro ni Gomina npa, ko ni nnkan se.
Onimoero Tunde
Awolana to je oga agba ileese OGBC ati Onimoero Dele Bolujoko to je oga agba
ileese telifisan OGTV ni a gbo pe Amosun da duro, to si je pe se lo so pe oun
feyin won ti ni tipatipa, ki won lo mu leta ifeyintin won wa ni kopekope.
Ase yi to gba enu
olori awon osise nipinle Ogun, Ogbeni Abayomi Sobande jade ni nnkan bi aago
mefa irole oni Wesde so pe ki won bere ifeyinti won lesekese pelu idupe wipe
won ku ise takuntakun fun akitiyan won nipa mimu idagbasoke baa won ileese
igbohunsafefe ati amohunmaworan ipinle Ogun.
Bo tile je pe ohun ti
olori awon osise ti koko so laaro nipe oun yoo ba Gomina sori lori iyanselodi
naa, toun yoo si jabo fun won leyin toun ba ti ba Amosun soro tan, sugbon ohun
to seni laanu ni pe iroyin idaduro awon oga agba ileese mejeeji lo mu wa fun
won.
Ohun tawon kan n so
nipe iwa ti Gomina Amosun hu yi ku die kaato, ko ye ko se bee, won ni se lo
dabi eni pe o fi owo ola gba won loju ni, nitori pe asiko tawon eeyan naa yoo
feyinti ko tii to.
No comments:
Post a Comment