Oba Adedapo Adewale
Tejuoso, Osile Oke Ona Egba, Karunwi keta ti soko oro sawon Musulumi nipa idi
ti ko fi fe maa ba won se po, paapaa lasiko to ba n se ayeye iranti igbade e.
Oba Tejuoso |
Oba Tejuoso soro yi loni
ojo Abameta Satide nibi asekagba ayeye odun mejidinlogbon to ti wa lori ite
awon babanla e ni gbagede aafin e to wa ni Sapon nilu Abeokuta.
Oba Karunwi keta so
pe oun ko fe lati maa bawon Musulumi se nitori epe ti won maa n se foun ti po ju,
ara oun ko si gba. Kabiyesi so pe odoodun lawon Musulumi maa n sepe foun pe
iyawo oun ko ni ju meta lo, eyi ko si te oun lorun.
O ni ko si odun kan
toun se, tabi ayeye kan toun se, tawon Musulumi ba ti wa nibe lati sadura tabi
soro, won o loro meji ju wipe iyawo oun ko nii lekan sii, ko nii kuro ni meta
to wa.
Oro yi jade latari
adura tawon agbarijo elesin naa ti ilu Oke Ona Egba se fun kabiyesi nibi
asekagba ayeye naa loni, nibi ti won tun ti lo anfaani e fawon oloye tuntun
mejila je. Kabiyesi so pe awon elesin oun ti wa, won si ti sadura, ti won ko si
menuba oro iyawo.
Kabiyesi atawon olori |
Awada lasan ni
kabiyesi foro naa se, nitori pe awon elesin naa ti soro to kan Kabiyesi
gbongbongbon pe kii yoju si mosalasi awon lati wa bawon ki jimo lakoko ti ayeye
iranti igbade e ba n lo lowo.
Won salaye siwaju pe
Oba Alake tilu Egba maa n lo ki jimo to ba n se ayeye e, bee naa ni Oba Olowu
maa n wo mosalasi, sugbon ti Kabiyesi Oba Tejuoso ko ri bee, nitori pe awon
feran e pupo, lo se maa n wu awon lati maa fee ri kabiyesi wipe ko wa maa ki
awon naa.
Oba Karunwi wa lo
ororo (anointing oil) lati fi yan awon oloye tuntun naa pelu oruko baba, omo
ati emi mimo, nigba to n so pe nnkan toun mo niyen ti won fi n yan Oba tabi
oloye. Kabiyesi ni aridaju e wa ninu bibeli, atipe ko se ese nibe ti won ba lo
ti ibile tabi isese, sugbon ororo ati omi loun mo nipa e.
L-R: Akingbogun, Asiwaju Iyalaje, Erelu Baage ati Baage |
Oba Tejuoso nigba to
n gbawon oloye tuntun naa lamoran, o so pe oye ilu dabi oro awon omo ile igbimo
asofin ti ko si oro esin nibe. O lawon to ba w anile igbimo asofin ko ni esin,
bi ko se pe won a maa jo ronu lati mu idagbasoke ba ilu ti won yan won le lori.
O ni asoju Oba Osile
Oke Ona Egba ni won je, nitori naa ki won rii daju wipe won ko si ipo naa loo,
atipe bi won ba sii lo, won n fi ori ade wole nita gbangba niyen.
Awon oye ti won je
naa ni Baage Oke Ona Egba; Erelu Baage Oke Ona Egba; Bashorun Oke Ona Egba;
Asiwaju Bada; Akinrogun Oke Ona Egba; Asiwaju Iyalaje Oke Ona Egba; Akingbogun Oke
Ona Egba; Daranijo Oke Ona Egba; Erelu Daranijo; Oluomo Oke Ona Egba; Yeye
Oluomo Oke Ona Egba ati Akeweje Oke Ona Egba.
No comments:
Post a Comment