Ojo manigbagbe lojo Aiku Sande, ojo kejidinlogbon
osu yi je nibi ti Aare fegbe National Association of Science Students, NASS ti
ile eko fasiti Olabisi Onabanjo to wa nilu Ago-Iwoye salabapade iku ojiji ninu
ijamba oko lopopona Ile-Ife, nilu Akure, ipinle Osun.
Gege bi AWIKONKO se gbo, Komureedi Adefuwa Christopher
to je Aare fegbe NASS nikan lo ku ninu ijamba naa lakoko ti won n bo nibi abewo
ti won se lo si Oke Idanre (Idanre Hills), tawon mokanlelogun toku ti won jo lo
si farapa.
Ijamba naa waye nigba ti won so pe tirela kan lo
doju ko won, to si gba won danu sinu igbo. Iyalenu lo je nigba ti won so pe
Christopher nikan lo ku ninu awon bii merinlelogun to wa ninu oko naa.
Opo awon to gbo nipa isele buruku yi ni won n so
orisirisi pe iku Christopher kii soju lasan, o lowo aye ninu. Bawon kan se n so
pe odomokunrin naa wa ninu egbe imule kan ni, bee lawon kan so pe o le je ogun
idile ni.
Sugbon gege bi iwadi ti AWIKONKO se, ko pe osu
meji mo ti Christopher maa kekoo gboye nipa imo sayensi ni iku muulo tue.
No comments:
Post a Comment