O ma se o, opo lo
fee mo idi ti ilumooka sorosoro ori redio ati telifisan, Ogbeni Kolawole
Adejojo topo mo si Kasnaty fit a moto, to si je pe okada lo n gun kaakiri
igboro. Oju ti yin, nitori pe odun 2013 lokunrin naa ta moto Camry onilekun
meji e, to si ra oko Honda bogini to tun ju eyi to n lo tele lo.
Bo tile je pe
iyalenu lo je fawon ololufe Kasnaty nigba ti won n ri kaakiri ori okada lodun
naa lohun, tawon elenu marimaso si n so pe nise lo ta moto e fi jeun, lai mo pe
o nibi to fee gba yo. Se won ni ile oba to jo, ewa lo bu si.
Bawon kan se n so pe
boya nitori ooteli kan to sese gba to n mojuto ti won pe ni DE-SUITE to wa ni egbe
ile Gomina Ibikunle Amosun,Ibara Housing niluu Abeokuta, bee lawon kan n so
nnkan min in.
Bo tile je pe
okunrin naa ko lo to osu meji to fi ti ooteli naa pa nitori gbese ti won so pe
eni to n lo ibe tele ti je sile, eyi to koja agbara sorosoro naa, sibe awon to sunmo
so pe owo kekere ko lo naa sibe, ko tun to tii pa.
Bee lawon kan so pe
ko ma je pe owo moto e to ta yii lo fi ran ara e loo si ileewe awon to n kose
ise iranse iyen pasito to sese pari. Ohun tawon kan ti e so nigba naa ni pe, ka
ni o le gun rin irinajo loo si ilu odi keji ni, o ba lara mu.
No comments:
Post a Comment