Yinni-yinni keni o
semi loro awon olopaa ipinle Ogun ri, nitori pe ko si ose kan kowo won ma tea
won adigunjale nipinle, ise takuntakun ti won si n se losan loru lo n fa ti won
fi n ri eran pa, nitori pe ode awon odaran ni won.
Ishola, Adetayo ati Adebayo |
Lojo Aje Monde to
koja yi lowo won tun bawon ogbologbo meta ninu ise adigunjale to je pe bi won
ti n fo ile, bee ni won n dawon awako lona lawon opopona kaakiri ipinle Ogun,
eyi to si ti ko iberubojo bawon araalu, paapaa awon to n wako ale.
Se Yoruba bo, won ni
ojo gbogbo ni ti ole, ojo kan soso si ni ti olohun, eyi to si lo ni ibamu pelu
bi owo se ba Abdul Azeez Ishola, Adetayo Gbenga ati Adebayo Samson lagbegbe
Ogere ni nnkan bi aago mefa koja ogun iseju, lakoko ti won tun n gbiyanju lati
dawon awako lona gba owo ati dukia lowo won.
AWIKONKO gbo pe
opopona Eko si Ibadan lawon ogbologbo odaran yi ti maa n sise ju, oru dudu si
ni won maa n sise won ju, ti won si maa n fagidi gba nnkan lowo awon onimoto.
Awon araalu to n koja
lo, to ku die ko ko sakolo won lo sare tete lo tu asiiri sita fawon olopaa to n
so togeeti Ogere, ko too di pe Ogbeni Paul Omiwole pelu awon olopaa toku lo
koju awon odaran naa ti won si ri won nibi ti won sapamo si, ti won n wa eni ti
yoo ko sakolo won.
“Aye mi baje” lorin ekun ti won mu bo enu nigba tawon olopaa ko won,
ti won si ko won de tesan. Agbenuso olopaa, Abimbola Oyeyemi nigba to soro naa
fun AWIKONKO, O so pe Ibon ilewo meji, ota ibon meje, aago owo meji, ero
ibanisoro mokanlelogun ati egberun merindinlogun ataabo ni won gba lowo won
loju ese ti won mu won ti won si tun ka gbogbo ese ti won ti n se bo.
Komisana Olopaa,
Ahmed Iliyasu ti wa pase pe ki awon olopaa digboluja FSARS lo tubo foro wa won
lenuwo. O si fokan awon araalu paapaa awon to n rin lona naa bale pe ko sewu
fun won mo nitori pea won yoo tun ko awon olopaa repete sopopona kaakiri lati
daabo bo emi ati dukia awon araalu.
No comments:
Post a Comment