E gba mi lowo awon awako Banki CBN to fee pami o – Gomina Amosun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 15, 2017

E gba mi lowo awon awako Banki CBN to fee pami o – Gomina Amosun

Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ti ke gbajari sijoba apapo orileede yi lati kilo fawon osise awako ileese Banki apapo orileede yi, iyen Central Bank of Nigeria lori ona ti won n gba lati wa awon oko akoworin ti won fi n gbe owo won, to si je pe se ni won fe e pa oun fawon omo ipinle Ogun.

Gomina Amosun
Amosun pariwo sita lakoko to n fehonu e han sawon awako naa nibi ijamba to ku die ko gbemi e lojobo Tosde ose to koja lopopona Eko si Ibadan, iyen Lagos Abeokuta Express-way atipe bi kii baa se opelope Olorun to ko Gomina Amosun yo ni, ohun ti a n ko yi ko ni a o ba maa ko, nitori ti won so pe awon awako naa mo-on-mo fe e se e lese ni.

AWIKONKO gbo pe kii se eleekeji re ti iru nkan bayii maa sele, iru ijamba yi ti sele ri nilu Abeokuta, to je pe kani awako to wa Gomina lojo naa ko ba tete fura lati jawo segbe ni, se ni won ko ba fi oko won ti gbogbo ara e je kikida irin gba oko Gomina danu, eyi to si see se ki Gomina ba ara nibi eeyan Kankan ko lero.

Isele to sele lose to koja tun je eyi to tun se awon araalu toro naa soju won ni kayeefi, to fi je ki won maa beere lowo ara won “ki lo pa Gomina Amosun ati awon awako Banki CBN papo, ti won fi n leri iku sira won,” nitori AWIKONKO gbo pe se lawon awako yi wa oko won niwakuwa wo aarin awon oko akoworin Gomina Amosun, ti won si fee gba won danu kuro laarin titi.

Gege bi AWIKONKO se gbo, won ni bi olori eso aabo Gomina se rii pe isele naa fee koja oju tawon fi n wo o, lo je ki okunrin naa tete ranse pajawiri sawon awako toku, wipe ki won se jeje, ki won si paaki oko won, nitori ti won so pe se lawon awako naa fee ofateeki awon oko akoworin Gomina Amosun lai wo ti ijamba to le sele, leyi to see se kemi awon araalu lo si.

Okunrin naa ni won so pe o pariwo sita pe kawon awako CBN to n wa oko niwakuwa sora won nitori pe Gomina ipinle Ogun wa ninu oko, ti won si n lo sibi ipade kan to se pataki.

Bi won se lawon awako yi gboro ikede naa, kaka ki won tee jeje, se ni won tun fi oko won gba oko e, atawon oko miran to tele Gomina, ti won si tun fi oko onirin won gba oko ti Gomina wa ninu e lojo naa.

AWIKONKO gbo pe, bawon eso aabo Gomina se rii pea won awako CBN yi ko fee gba, lo je ki won wa oko won siwaju won lati dawon duro koju won, ki won si kilo fun won. Se ni isele to sele lojo dabi fiimu agbelewo loju awon araalu to sele loju won.

“Egba mi, ki lo n se yin” lariwo ti won ni Gomina Amosun pa fawon eeyan yi lojo naa, nitori ko seni to maa foju ri isele naa, ti ko nii so pe se ni ki ijoba gbase lowo awon awako Banki CBN lojo naa, nitori ti won so pe iwa aibikita ni won hu lojo naa, atipe paapaa Gomina ilu kan ni won seru e fun.

Amosun nigba toun naa n soro, o so pe iwa tawon eeyan naa hu tapa sofin orileede yi, paapaa ofin to de oko wiwa. O tesiwaju pe “Bi iru eyi ba le sele si Gomina to si wa lori aleefa nilu to je Gomina si, melomelo lawon araalu to maa ti ko si pampe won, to si je pe ise aje lo n gbe opo won lo sibi ti won n lo.”

Nibe lo ti so pe ki ijoba apapo tete wa nnkan se si bawon awako ijoba, paapaa awon awako CBN se n wa oko laarin ilu, nitori emi ati dukia awon araalu ko jo won loju.

Amosun wa so pe oun ko ni fi aaye gba iwakuwa laarin ilu mo lati akoko naa, nitori naa lawon yoo tun se wo ona miran tawon tun le gba yo nipa oro oko wiwa, eyi ti yoo maa daabobo emi ati dukia awon araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI