Lati
nnkan bi osu kan seyin lawon osise ileese redio naa ti n ko leta ikilo fun
iyanse-lodi sijoba, sugbon kaka ki ijoba ipinle Ogun gba leta naa ka, ko si san
owo won fun won lasiko, eremode ni won ni ijoba ipinle Ogun fi leta naa se,
wipe won ko to bee lati lo fun iyanse lodi.
Lojo
Aiku Sannde to koja yi lawon osise naa se ipade kan, eyi ti won fi to awon
agbaagba kan nidi ise iroyin, to fi mo alaga egbe oniroyin nipinle Ogun, Ogbeni
Abiodun Ogundipe leti pe ona wo lawon tun le gba kawon ma lo si iyanselodi yi,
leyin ipade naa ni won tun ko leta olojo meta miran sijoba wipe awon yoo bere
iyanse l’Ojoru Wesde bi won ko ba tete da si oro won, nitori pe iya n je won,
gbogbo awon to si n ri won ni won ro o pea won gbowo osu, to si je pe gbese
tawon ti je sile ko see ko.
Ni
nnkan bi aago merin aabo aaro Ojoru Wesde lawon osise kookan ti de si ogba
ileese redio naa wipe bebe yoo sele, pepeye yoo gbomo adie pon, wahala maa so
nitori ti won so pe ko seni to maa wonu ogba redio naa lati sise, afi ti ijoba
Amosun ba dawon lohun, ko si san owo osu merin won fun won.
Sugbon
nigba to di aago marun geerege lawon osise naa loo ti awon ilekun yara
igbohunsafefe atawon enu ona abawole sinu ogba ileese redio OGBC naa wipe ko
seni ti yoo wole ninu awon oga agba atawon alakoso ileese naa.
Awon
to lewaju ehonu iyanselodi tawon osise redio naa bere ni Ogbeni Abiodun
Ogundipe to je Alaga fegbe akoroyin ati Ogbeni Ayo Aina, Alaga fegbe awon osise
ileese redio ati telefisan nipinle Ogun.
Nigba
to n ba AWIKONKO soro lori iyanselodi naa, Ogbeni Ogundipe so pe awon ko ni
pada seyin, ayafi ti ijoba ipinle Ogun ba san gbogbo owo to je awon osise
ileese redio naa, nitori pe oun ko le la oju oun sile ki iya maa je awon eeyan
won.
AWIKONKO
gbo pe gbogbo eto to ye kawon osise naa se nipa iyanselodi ni won se, nitori pe
won ni won ti koko ko iwe ikilo iyanselodi olojo mokanlelogun, olojo meje ati
olojo meta, leyi ti won ko le so pe won jebi ijoba labe ofin.
Ogundipe
tesiwaju pe Oga awon osise nipinle Ogun, Ogbeni Abayomi Sobande ti da si oro
naa wipe kawon osise naa lo ni suuru, o si se ileri wipe won yoo ri owo ijoba
ipinle ogun laipe, nitori pe ijoba alaanu ni ijoba ipinle Ogun.
Sugbon
o so pe oun mo pe ileri ori ahon lasan ni, iyen ko so pe kawon dawo iyanselodi
naa duro ayafi ti ijoba ba se nnkan tawon n fe fawon eeyan won lasiko.
Yato
sawon owo osu ajeele, ijoba ipinle Ogun tun je awon ni owo ifeyintin ti won
ti n yo lati odun 2012 titi di odun 2017, eyi to ti le ni aadota milionu naira.
Bakanna ni won tun so wipe owo kan to je owo ile ijoba apapo, iyen National
Housing Fund to je milionu meji naira ni ijoba ko tii san fawon.
Awon
owo ti won tun ni ijoba ipinle Ogun je awon ni N148,260,000 to je owo to je eto
won; N76.8 million to je gege bi owo ajeele; N45 million to je gege bi owo
ifeyinti; N464,000 to je owo egbe fodun 2017 ati N6million to je owo alajeseku
tipatipa ti won n se labe ijoba.
No comments:
Post a Comment