Gbajumo dirun-dirun
(hairdresser) kan ladugbo Onabola Owotutu ni Somolu nipinle Eko, yetunde
Oladipupo topo mo si Iyabo la gbo pe o ti gbe oogun apefon (insecticide) mu
nitori gbese ti won so pe o je enikan.
Gege bi AWIKONKO se
gbo, nirole ojo Eti Fraide to koja yi won ni ore e kan wa ki, bo tile je pe ko
se ni to le so pato idi tiyen fi wa ki, sugbon ohun ti a gbo nipe, ko pe ti ore
e yi lo, la gbo pe Yetunde gbe Yetunde gbe oogun apefon to ti ra lati aaro mu.
Awon araadugbo ti
won ri nibi to ti n lo inu mole ni won sare gbee lo si osibitu kan ni Gbagada
lati doola emi e, sugbon nigba ti won fi maa gbe sori beedi, o ti dake, elemin
ti gba a.
Yetunde, iya olomo
merin la gbo pe o je omo bibi Ijebu-Igbo nipinle Ogun lo gba owo to je ogoje
ataabo naira (N150,000) nile ifowopamo microfinance tawon to gba owo lowo e si
ti n daamu e pe ko tete wa a san owo to je won.
Lara awon to ba
AWIKONKO soro nipa omobinrin naa, won ni Abuja loko e ti n sise, to si je pe
eekookan lo maa n wale lati yoju si won, won loko naa ko bikita lati maa se
ojuse e gege bi baba ati oko, eyi lo fa ti won so pe Yetunde fi lo o gba owo
naa, ko si le maa fi ri nnkan ta.
Sugbon se ni won so
pe, oja to fi owo naa ra ko ya, bukata omo merin lo si je ko je pe owo to n pa,
bukata ounje ati owo ileewe awon omo naa lo fi n gbo, eyi ti ko fun ni anfaani
lati maa ri owo dapada fawon banki to ya owo naa lowo won.
Won ni nigba ti wahala
tawon osise banki to ti lo yawo naa n fun lo fi woo pe koun gbemi ara oun ko
too pe ju, ki oju ma baa tii ladugbo.
Enikan lara awon
araadugbo to tun ba AWIKONKO soro so pe awon ore e meji ti waa ki, to si sin
won lo ni nnkan bi aago meje irole, sugbon nigba to n pada bo lo ya sinu soobu
kan to wa niwaju ita ile to n gbe, to sir a oogun apefon.
O ni leyin to ra
oogun apefon naa tan, lo beere lowo eni to ra a lowo pe ko foun ni ora (nylon),
sugbon tiyen so pe ko si. Inu iro aso to wo lo so pe o yi kini naa mo. O nib o se
n gun oke ile to n gbe lati maa wonu yara lo, lo mu oogun apefon naa tan
bamubamu.
Loju ese lo ti bere
sii je irora, to si n lo inu mole, ko too sare pe omo e, omodun marun to wa
nitori lati wa ran an lowo, ko si baa pe awon agba to wa layika. Ileele nibi to
ti n yi kiri ni won ti ri pelu ike apefon to mu, nibe lawon eeyan ti pariwo sit
ape ki won gba awon.
Lesekese ni won ti
seto lati gbe e lo si osibitu boya won si le ra emi e pada, sugbon won ni epa
ko boro mo nigba ti won fi maa de osibitu jenera to wa lagbegbe Gbagada nitori
ti won so pe dokita marun ni won ni won lakaka lati du emi e.
Aaro ojo Abameta Satide ni won loo dake si osibitu naa nitori ti won so pe kini to mu ti je ifun e koja aye ki won too gbe debe.
No comments:
Post a Comment