Alake tile Egba, Oba
Adedotun Aremu Gbadebo, Okukenu kerin ti rawo ebe sijoba apapo lori oro ileeko
fasiti ise ogbin, Federal University of Agriculture, Abeokuta nitori eka ikekoo
kan to n ri si kiko nipa isakoso, iyen College of Management Sciences, COLMAS
ti won fagile laipe yi.
Alake tile Egba |
Bi e o ba gbagbe,
laipe yi Minisita foro eko lorileede yi ti pase pe ki awon fasiti to doju ko
ila eko kan tesiwaju ninu ilana eko ti won yan laayo, ki won yo awon ilana eko
ti won ko mo won mo sugbon ti won n sise lori e kuro. Eyi tab a opo awon
fasiti, Poli atawon ile eko giga miran lorileede yi, to si fee fa owo aago won
seyin.
Nibe ni Alake ti so
pe ki ijoba apapo boju aanu wo fasiti FUNAAB atawon akekoo to ti wa lenu eko
naa ko too gbe ase naa jade, nitori pe ko sibi ti won fee lo, atipe saa awon
akekoo kan ti fee pari, to si je pe se lawon akekoo kan sese wole, ko too dipe won
gbe ase naa jade.
O so pe opo awon eleto
eko, obi, alagbato, osise, akekoo atawon toro naa kan nipinle Ogun ati agbegbe
e lo ti fehonu han, ti won si ti wa n ba oun lati wa nnkan se soro naa, eyi to
si se oun laanu wipe oro naa n fe abojuto daadaa, atipe ki won yi ase naa pada.
Alake ran ijoba
orileede Naijiria leti pe osu kesan odun 2011 ni Fasiti FUNAAB da eka ikekoo
COLMAS sile latari ase ijoba to koja lo, iyen ijoba Dokita Ebele Jonathan to
pase pe ki awon fasiti ma se koju mo eka ikekoo kan soso, ki won yabara, ki won
si fi awon eto eko miran si ilana eko ti won n ko nitori ki ise le rorun fawon
ile eko giga to ku.
O ni bi won ba so pe
ki fasiti FUNAAB dawo eka ikekoo naa duro, a je pe won ko fe kawon akekoo je
anfaani imo igbalode nipa isakoso (Management Sciences) bii isiro (Accounting),
ile ifowopamo ati isiro owo (Banking and Finance), eto sile (Business
Administration) ati eko bi a se n da ise sile (Enterpreneurial). O ni opo awon
akekoo to le ni egberun mewa lo saba maa n gba foomu si awon eka ikekoo yi
lodoodun tawon si ma n gba to eedegbeta ninu won gege bi ajo JAMBU se maa n fun
won.
Alake tesiwaju pe
eka ikekoo yi ti won da sile ni Abeokuta, Makurdi ati Umudike ti mu ki eto oro
aje orileede yi lo soke paapaa lawon ilu to faaye ile gba won lalejo. Tawon ti
ko rowo mu lo senu si ti n fun awon alaini lounje.
Gege bi AWIKONKO se
gbo, akekoo to to egberun kan ni won ti keko gboye laarin odun mefa ti won da
eka ikekoo naa siile. Bee lo si je pe opo awon eeyan nipinle Ogun lo je pe owo
to n wole fun won ko to n kan, eyi ti ko si ni fun won lanfaani lati mu awon
omo won lo sile eko giga towo won lo soke gegere.
Alake ni oro naa n
fe agbeyewo ni kankan nitori pe awon igbese to tun le fa oro aje orileede yi lo
seyin ni Minisita foro eko lorileede yi gunle, ki won si tete wa atunse si.
No comments:
Post a Comment