Awon meteeta |
Lojo Aiku
Sande to lo lohun ni Imaamu Muhaleem Iskeel Olakewu labe ijo Salamu-Llahi
Centre for Islamic Culture to fikale silu Abeokuta se Wolimo fawon meta to kun
oju osuwon lati gba iyanda.
Awon meta
naa ni Obadara Fathia, Odedina Muh Faruuq ati Obadara Ibrahim.
Lojo naa ni won tun lo anfaani naa lati fi se ikowojo fun ijo ti won n ko lowo.
Okan lara obi awon omo
to se Wolimo naa, Ogbeni Akeem Obadara nigba to n bakoroyin wa soro so pe
idunnu ati oriire nla lo je foun wipe meji ninu awon omo oun se aseyori ninu
eko ti won lo ko naa.
Arabinrin Obadara
nigba toun naa n soro so pe odun to koja lo ye kawon omo naa ti se wolimo yi
sugbon oun gbogbo lo ye Olorun to fi je pe odun yi ni won se, nitori pe won ti
dangajia ninu kika kurani.
Imaamu Olakewu wa lo
akoko naa lati fi dupe lowo Olohun fun anfaani ati ona ti ayeye naa gba waye
atawon agbaagba ninu esin naa to wa sibe lati ilu Ibadan.
Bakanna lo wa gbawon
Musulumi lamoran lati maa ran awon omo won lo sile keu ki won si tun rii daju
pe won n se Wolimo fun won.
No comments:
Post a Comment