Bi e ba wa nibi ti obinrin yi ti n korin, se le maa ro pe Oloogbe
Batili Alake lo n korin ni, bo tile je pe ohun tawon kan n so tele ni wipe
leyin iku gbajumo Olorin Waka naa, ko seni to tun le dabi e mo nitori ti won ko
le so boya a ri eni to ko nise orin tabi ko je pe ninu awon omo e gbegba orin,
sugbon oro ko ri bee, nigba ti AWIKONKO ba Alaaja Kuburat Oritoke, eni to
filu Ago Iwoye sebugbe pade nilu Abeokuta laipe yi, to si so awon ipenija ati
adojuko e, eyi ti ko tii fun ni anfaani lati se rekoodu ti e jade, bo tile je
pe orisirisi ode ariya lo ti n korin.
Alaaja Kubura Oritoke |
Alaaja Oritoke nigba to n soro so pe ilumooka olorin Fuji nni, Alaaji
Wasiu Alabi Pasuma ba oun lenu ise orin ni nitori pe odun 1984 loun ti bere sii
korin ko too dipe Pasuma ronu lati bere sii korin, ki aye too mo.
O ni Pasuma maa n wa sibi toun ba ti korin, ko too gbegba orin ti e
naa, to si maa n ki oun loju agbo bo tile je pe okunrin naa ko le ranti oun mo
nitori pea won eeyan ti po, sugbon oun mo pe tawon ba si jo soro, o see se ko
ranti oun.
Omo bibi ilu Ago Iwoye yi so pe leyin toun pari eko ni pamari siisi ni
baba oun so pe koun ma da ara oun laamu lati lo sile iwe mo nitori awon eeyan
ti so pe ise orin lounmaa se toun ba dagba. “Won wa mu mi lo si odo Oloogbe
Batili Alake ni Ijebu Igbo lati lo ko ise orin, ti mo si lo odun mejo nibe.
Odun 1977 ni mo de odo Batili Alake, 1983 ni mo se firidoomu, ti mo gbominira.”
O ni idi niyi toun ko fi ronu lati lo ko ise min in nitori ayanmo orin
toun gbe wa saye. O tesiwaju pe odun kan, iyen odun Sofari tawon maa n se
labule nigba naa, toun si maa n ko awon omode jo lati korin kaakiri aba, tawon
eeyan si maa n fun won lowo lawon eeyan ti lo so fun baba ouun pe ibi toun ti
le lokiki niyen, ki won lo fimi sodo eni ti yoo tubo ko mi nise orin.
Alaaja Oritoke tun so fun AWIKONKO pe awon ipenija ati adojuko toun
ti ba pade ni ko je koun tii se awo rekoodu jade lati odun 1984 to ti gbominira
lodo oga e, Batili Alake to ko o nise naa.
O ni awon oko toun n fe lo n se sababi ifaseyin ati ijakule toun ba
pade lodo awon to ye ko ran oun lowo lati gbe orin jade, koun naa si di gbajumo
laarin awon olorin Fuji, paapaa ni ti orin Waka toun yan laayo nitori pe won ko
fe koun korin.
“Awon oko ti mo n fe nigba yen, opo won ni won je idena lodo awon to ye
ko ran mi lowo, sugbon igba ti mo wa da duro, ti mo sunmo egbe FUMAN, ti mo n
sunmo awon agbaagba bi alaga, ti won si n mu mi jade, lo ti n fi okan mi bale
pe laipe, maa se rekoodu jade. Mi o tii so ireti nu wipe mi o le se rekoodu
jade, niwon igba ti mi o bai ti ku, mo nigbagbo pe oluranlowo n bo.”
O wa rawo ebe sawon eeyan pe ki won siju aanu wo oun lati ma je ki
talenti oun ku. O ni oun na ko duro, nitori pe awon to ye koun sunmo loun n sa
gbogbo agbara oun lati rii pe oun naa se rekoodu toun jade nitori pe orin wa nile repete lati fi se rekoodu.
No comments:
Post a Comment