Bee
ni Ijoba ipinle Ekiti tun ti dide iranlowo
Bisi Omologbalogba |
Ko je tuntun pe eni
to sunmo gbajumo Oloogbe Moji Olaiya ju ninu awon osere tiata ni Bisi Ibidapo-Obe
topo mo si Bisi Omologbalogba nitori pe ore kori-kosun ni won je, to si je ko
si nnkan tawon mejeeji ko mo nipa ara awon, paapaa nipa oro idile won.
Bi e ba so pe tegbon
taburo ni won, e o paro, bi e ba si so pe ore timotimo ni won, e o jayo pa
nitori pe ibi ti e ba ti ri Moji Olaiya naa le ti maa ri Bisi Omologbalogba bo
tile je pe won kii se eje kanna an.
Nigba ti won woo pe
tani won tun le pe lati beere oro lowo e lori bi isinku Oloogbe naa yoo se ri,
latari wahala to tidi e yo nipa ibi ti won fe sin in si, ohun to so nipe oun ko
loro lati so nipa.
Bisi Omologbalogba
so pe ki won ma yo oun lenu, ki won ma beere iku to pa ore oun lowo oun, ki won
si fi oun sile na nitori pe ara oun ko tii bale, oun ko tii mo ibi toun ti fee
bere, atipe ta loun yoo tun foro lo.
O so pe ironu iku
enikeji oun lo si wa lara oun atipe eni to ba fee mo nipa isinku Moji Olaiya,
ko maa bo mi Magodo lati wa foju ri nnkan to n lo.
Yomi Fash Lanso |
Nigba toun naa n
soro nipa bi isnku Moji Olaiya yoo se lo, Yomi Fash-lanso to farahan ninu fiimu
akoko ti Moji Olaiya yoo ti kopa, iyen Owo
Ale so pe enikan soso lo si lodi si wipe ki won sin Moji silu Canada ni omo
e Adun to je akeko ile eko Backcock ni Remo. O loun nikan lo si le so idi e to
fi so pe dandan ni ki won gbe iya oun pada wa si Naijiria.
Yomi so pe bi eeyan
ba maa gbe oku wa lati Canada, o kere tan, egberun metadinlogun dola ($17,000)
lo maa na won, atipe o wa ku sawon ebi naa lowo lori igbese ti won ba fee gbe.
Nigba to n soro lori
aheso wipe oro naa lowo aye ninu nipa bawon osere tiata se n fo sanle ku lasiko
yi, Yomi so pe oun ko nigbagbo ninu wipe ise aye ni, nitori pe onikaluku lo ti
ni akosile igba to maa ku.
O ni opo eeyan lo n
ku lojumo, sugbon tawon to loruko lawujo ba ku, orisirisi oro lo maa maa jade
sita. O ni ki won gbenu kuro lori wipe ise aye ni, nitori pe awaya malo kan ko
si.
Sugbon ni bayii,
AWIKONKO gbo pe oko ti Moji bimo osu meji yi fun, eni to filu Abuja sebugbe ti
wa nilu Eko lati Ojobo Tosde toro naa ti sele, tiroyin si ti kan kaakiri
agbaye, bo tile je pe oun naa gba pe ki won sin iyawo oun si Canada nitori aisi
owo lati fi gbe e wale ko too dipe ijoba ipinle Ekiti dide fun iranlowo.
Aago merin irole ojo
Eti Fraide to koja yi lo ye ki won sin Moji silu Canada pelu gbogbo eto ti won
ti se nibe ni ilana Musulumi, sugbon ti won da won lowo ko pe ko jo.
No comments:
Post a Comment