Gbajumo osere tiata nni, to tun
je apanilerin, Ogbeni Bolaji Amusan topo mo si Mista Latin soro, ile kun lojo
to ba AWIKONKO soro nipa Ajo Alaanu Mista Latin Foundation to da sile lati maa
fi ran awon araalu lowo. Bo tile je pe opo lo n woye pe bawo ni okunrin naa se
n see, ti ise tiata ko fi di ajo to da sile naa lowo. Eyi lo mu ki AWIKONKO lo
foro wa Mista Latin lenu wo. E iforowero naa bo se lo.
MR LATIN: E se, Mr. Latin Foundation ni a pe akole ajo alaanu naa, a
wa fi sisale e pe “Gba emi kan la loni in”, emi la n du, a kii se Olorun a si
ki n se dokita, sugbon mo wo wi pe nigba ti mo kere, mo jiya, baba mi o lowo,
iya mi naa o lowo, awon to ni owo naa la n sare lo baa.
Ninu awon ta n sare lo ba yen,
won n lawon ko le se fun wa, won le wa danu, ohun la fi wo pe, ti
Olorun ba gbe awa naa ga ka huwa lati ran awon eeyan lowo, ka ma se bi
awon ti o ran wa lowo, tori opolopo awon ti won o ran wa lowo nigbayen ni won
ko lowo mo loni in. Opolopo awon ti won si ran wa lowo ni gba yen owo won o
tori e parun. Bi o ran eeyan lowo ko ni kowo e ko tan, boo si ran eeyan lowo ko
ni ko tori e lowo ju Dangote lo.
Nigba ti mo dagba ti mo n sise
tiata awon eeyan ro pe mo ni owo lowo ni, ile mi, ofisi mi, lokesan, Iranlowo
ni won n ba wa, Awon min a ni, mi o rowo ile san, omo mi wa nile iwosan, iyawo
mi n saisan, iyawo mi fee bimo, melo lagbara mi ka lati le da se, nigba ti mi o
ki n se ijoba, ohun ni mo se wa roo wi pe e je ka da ajo alaanu yi sile
lati le san esan fun awon awujo to gbe wa de ibi ti a de loni in, ka ran awon
eeyan lowo niwonba ti agbara wa ba ka, eyi ti agbara wa ko ba ka, aa pe awon eeyan
ti won ni eje aanu lara lati ba wa saanu. Opolopo igba kii se owo la n gba
lowo awon eeyan, elomin le nilo keke aro, a o wo eeyan to lagbara niluu
ka so fun won pe ki won joo, e fun wa ni keke aro meji ka fun awon eeyan yi,
won a fun wa, aa si dupe lowo won, ati beebee lo.
AWIKONKO: Odun wo gan le da ajo naa sile?
MR LATIN: Odun 2011 la ti daa sile, sugbon ise bere lori e lodun
2012, nitori nigba ta da sile a se iforuko sile, leyin naa la koko wo ibi
tawon eeyan yoo ti je anfaani ajo alaanu yii, Ka sa so pe osu kewa odun
naa nise bere ni pereu.
AWIKONKO: Ona wo lawon eeyan n gba lati je anfaani ajo yii?
MR LATIN: Awon eeyan kooakan n ran wa lowo, kii se owo ni won n
fun wa, a le fe loo se ikede lori oro to se koko , Iranlowo tawon eeyan n
fun wa nigba min, elomin le fun wa ni moto pe ka gbee lo fi se ipolongo, elomin
le fun wa ni irinse ta maa lo, awon nnkan tawon eeyan si n se fun wa lowo lowo
niyen, sugbon nnkan tawa naa ni lapo ara wa la koko n lo bayii, nigba tawon
eeyan ba wa ri pe a n se iwon ta le se ta, gbe dide, awon eleyinju aanu a
le dide iranlowo si wa.
AWIKONKO: Bawo lawon araalu se tewogba ajo yii?
MR LATIN: Nnkan ta wa n lo ni oruko ta a ni to je pe Olorun lo fun wa
ati awon araalu ti won tun ba wa gbe, iyen ni idameji taa koko n lo bayii lati
bawon eeyan wa soro, lati pe awon to danto min wa. Lenu igba taa bere yii
aimoye awon eeyan to n wa fun owo ileewe, ni Poli, ni Yunifasiti, ni Koleeji,
nileewe onipele keji, ati ileewe alakoobere ta n se fun won lapo ara wa. Iwonba
owo ta maa fi jeun la maa pin mo ara wa lowo, nigba to je pe ki aye le da naa
ni gbogbo wa jo n se, nitori naa bo je ogun naira lo ku taa fe fi jeun teni kan
si nilo idaji e, awa naa a fun, a n yi gbogbo e mo ara won ni.
AWIKONKO: Se ipinle Ogun nikan ni abi orile ede Naijiria ni ajo alaanu
yii wa fun?
MR LATIN: Rara o. Kaakiri Naijiria ati gbogbo agbaye lo wa fun,
sugbon awon oloyinbo ma n so pe “Ile la ti n keso rode”. Ninu ajo wa, a ti ni
Hausa, a tun ni awon eeyan ti won mo ede Ibo so daadaa, a ni awon omo Igbira
lodo wa, ati beebee lo. A yipo gbogbo ijoba ibile to wa nipinle Ogu, a ti lo si
ipinle Oyo, ati beebee lo.
AWIKONKO: Awon wo lo wa ninu igbimo Mr. Latin Foundation yi?
MR LATIN: Baba egbe wa ni Wasiu Ayinde Marshal,, Alaaji Sefiu Alao je
okan lara awon Baba Isale wa, Alaaji Wasiu Alabi Pasuma naa baba isale ni, a
tun ni awon eeyan loke okun. Nnkan ta fi ko awon osere ati olorin jo ni pe yoo
tun tawon eeyan ji pepe, Wasiu Ayinde Marshal gege bi olorin, o ti gbe awon
eeyan dide pupo ni ona e, ko to bere orin ni won ti n pariwo pe orin soro
ko o, sugbon nigba toun de, o so gbogbo e di irorun fawon eeyan, o so orin di
nnkan ti tomode tagba n ko nirorun, o je awokose nidi ise orin. Wasiu Alabi
Pasuma je eni to lawo sawon eeyan, bo se n ko awon omode mora lo n
ko awon agba mora, Sefiu Alao naa bakan naa lori, iru awon ta n soro nipa e
niyen lati tawon eeyan ji.
AWIKONKO: Bawo le se n koju mo ajo yi pelu isetiata ti ko si ni di
arawon lowo?
MR LATIN: Gbogbo e naa la n se papo ti okan o le di ekeji lowo rara,
ise ajo ta n se kii se ojoojumo, ise tiata kii se ojoojumo, mi o le tori ajo
alaanu yii ki n so pe mi o se tiata mo, ti mo ba se bee, o tun mo si pe owo ajo
ni mo fe maa na niyen, ise mi wa loto ti mo n se, ajo alaanu je lati le ran awon eeyan
lowo ni.
----------------------------------------------------------------
E mo daju pe: Iforowero yi ti le ni odun meji
--------------------------------------------------------
----------------------------------------------------------------
E mo daju pe: Iforowero yi ti le ni odun meji
--------------------------------------------------------
No comments:
Post a Comment