Mi o kowe fise sile o – Akowe ipinle Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 13, 2017

Mi o kowe fise sile o – Akowe ipinle Ogun

“E gba mi, e gba mi, nibo le ti gbo” lariwo ti Amofin Taiwo Adeoluwa to je akowe ipinle Ogun n pa nigba to n ba AWIKONKO soro nipa awuyewuye to n lo kaakiri pe o ti kowe fipo sile gege bi akowe fun ipinle naa.

Adeoluwa so pe iro to jinna si ooto loro naa, atipe aheso lasan ni, o lawon ota ipinle Ogun lo n gbe ayederu iroyin naa kaakiri, atipe eni to see se ko gbe oro aheso naa sese kuro lakolo ijoba ipinle Ogun laipe yi nitori wahala to ko ara e si.

Ninu oro e, o so pe “Eyin oniroyin yi paapaa, sebi e si ri mi lana to je ise ipinle Ogun ni mo wa se nibi ti a ti pade, se eni to ba ti kowe fise sile tun maa n lo sawon ode to je tipinle naa mo ni. Mi o kowe fise sile o. awon to n gbe iroyin naa kiri ko nise lati se ni, o ye ki won lo wa ise ko, eyi ti ko ni je ki won ri aaye lati maa gbe aheso kaakiri.

AWIKONKO gbo pe gbajumo onimo nip ero ayelujara nni, Ojo Emmanuel lo gbe oro naa sita fawon eeyan lati gbo, bo tile je pe okunrin naa maa n so awon otito nigba miran, sugbon eyi to gbe jade yii, iro patapata ni.

Okunrin kan toruko e je, Daniel Oludipe nigba toun naa n fesi si iroyin naa, o so pe “Pelu pe mo ka iroyin to soju saara wipe iro ni nipa Amofin Taiwo Adeoluwa, akowe ipinle Ogun, mo pe e lori aago gege bo se je egbon fun mi ati alajosepo kanna ti a je nibi Egba Economic Summit Group. O fi mi lokan bale wipe ko si nkan to jo be, atipe oun si lo sise ipinle Ogun ni ana ni lakoko tawon iyawo gomina kaakiri ile Yoruba wa sipinle Ogun. Kawon araalu ma se gba iroyin naa bi eni gba igba oti."

Sugbon ohun ti eni to sagbateru ayederu iroyin yi n so nipe iro ni Amofin n pa, atipe igbese lati fipo naa sile lo n se lowo.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI