Mi o di sorosoro tori mo lohun bi Gbenga Adeboye – Van Garuba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 9, 2017

Mi o di sorosoro tori mo lohun bi Gbenga Adeboye – Van Garuba

Bi a ba n so nipa awon to mu ohun Oloogbe Gbenga Adeboye, odu ni Van Garuba, kii saimo foloko.

Van Garuba

Okan lara awon omo egbe sorosoro to daduro iyen Freelance and Independent Broadcasters’ Association of Nigeria, FIBAN nipinle Ogun, Ogbeni Ibrahim Garuba Abubakar Kehinde topo mo si Van Garuba ti so pe kii se oro toun le so bii Oloogbe Gbenga Adeboye lo je koun gbegba sorosoro.

Bo tile je pe opo lo n so kaakiri pe se ni Van Garuba mon on mo lo ko bi Oloogbe Gbenga Adeboye se n soro lati le je kawon eeyan tete mo. Van Garuba soro yi lopin ose to koja nigba to n dahun ibeere lowo AWIKONKO nipa awon ipenija to ti n ba pade latigba to ti bere ise sorosoro lodun 2009.

Ninu awon orin to n pop o lowo tawon eeyan n gbo nigboro ni won ti so pe ohun Gbenga Adeboye lo lo ninu e, eyi ti won fi n so pe nitori ko baa le tete lokiki lo fi woo pe koun gbona ti Gbenga Adeboye yo.

O ni ede toun n so, gege bi omo Ilorin to dagba silu Oyo lo foun lanfaani lati maa so ede naa to fee dabii ti Gbenga Adeboye. O so pe bawo ni yoo se rorun fun eeyan lati mu ohun eni ti won ko jo soro ri, tabi ti won ko jo ri ara won soju ri, “ko see se.”

Ninu oro e “Opo eeyan ni ko mo pe o maa n soro lati mu ohun eni ti won ko jo duro soro papo ri, atipe nkan tawon eeyan ko mo nipa Gbenga Adeboye ni wipe ki o to o le lo ohun elomiran, aa ti ri bi eni naa se n soro loju-koroju, ti won a si jo sefe.”

Bakanna lo tun so pe oun ko le da orin Gbenga Adeoye kan ko lati ibere dopin. Iyen nikan tun ko, gbogbo ohun ti Gbenga Adeboye nlo ni Olorun fi sohun lofun, “Abi se mo le lo o ji ohun e yo ninu saare ni. Nkan ti o ti mi debi ki n maa soro bii Gbenga Adeboye ni pe mo rii pe Olorun fun mi ni imo nipa e, awon ijinle ede si maa n so si emi naa lokan. Bee lawon oro ogbon ati atawon okodoro oro fi enu mi sebugbe. Bakanna lawon efe maa n so simi lokan bi eko gbigbona se maa n so ninu ape.”

Lara awon eto ti Van Garuba n se lori redio ni “On sele” ni Family FM to wa nilu Abeokuta. Bee lo tu n se MC kaakiri ode ariya tawon eeyan si n kan sara si pe ise e ko lafiwe. Fawon to ba fee pe fun MC, awon nomba ti e le pee si ni 08167288192 ati 08058439737.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI