Ijo Ori-Oke Ina ati Ise Iyanu, iyen Mountain of Fire and Miracles Ministries, S/W Region 1 headquarters, Abeokuta ti yan igbimo igbeyawo eleni mesan titun ti won yoo maa sakoso eto igbeyawo to ba fee waye ninu ijo naa.
Awon oloye egbe tuntun |
Lojo Aiku
Sande to lo lohun ni eto ifilole awon igbimo yi waye ninu ijo naa to wa adojuko
papa isere Muda Lawal, Asero Abeokuta, eyi ti won tun fi se idupe fun Pasito
Ayo Owolabi ti won gbe wa fun won fun ti awon oluso agutan ti won yi pepe po,
iyen Pulpit Rotation olosu kan to maa n waye ninu ijo naa kaakiri agbaye
lodoodun.
Awon mesan
naa ni Pasito Sunday Aderibigbe, Pasito Sunday Akinbola, Pasito Samuel
Emuelosi, Pasito Olaniyi Gabriel, Pasito Omoniyi Omowale, Pasito Idowu Adepeju,
Arabinrin Olugbemi Oluwafunmilayo, Arabinrin Oluremi Adejumoke ati Arabinrin
Kuye toun ti lo fun ise iranse ti won yan an fun.
Alaga
igbimo igbeyawo fun ijo MFM lagbaye, Pasito S.A Laoye nigba to n fi awon eeyan
naa han ijo lojo naa so pe kii se pe awon kan mu awon eeyan naa lasan, tawon si
fi won je oye yi, bi ko se pe won ti la orisirisi idanileko koja, ti won si tun
peregede ninu idanwo ti won se fun won. O ni oun gbogbo lo ni eto ati liana
ninu ijo MFM, eyi ti igbeyawo je okan pataki tawon ko gbodo fowo yepere mu.
Eyi lo fa
ti won fi seto lati maa yan awon igbimo ti yoo maa sakoso igbeyawo to ba fe e
waye. O ni leyin ti okunrin ba ti ri obinrin to ba wu, awon igbimo yi ni won
yoo seto to ye lati je kawon mejeeji ye lati segbeyawo.
Gege bi
IROYIN OWURO se gbo, ni nnkan bi odun meta seyin ni won ti koko yan awon igbimo
igbeyawo kan leyin ti ajo to n ri si igbeyawo lorileede Naijiria ti fun won
niwe ase l’Abuja lati maa tesiwaju nipa sise igbeyawo ninu ijo, sugbon leyin ti
won rii pe ijo naa ti n dagba sii pelu awon ijo tuntun ti won n da sile, lo je
ki won tu won ka nitori ninu awon ti won yan nigba naa ni won ti fi da ijo
miran sile labe MFM Asero.
No comments:
Post a Comment