Ajo to n ri si
ilogeere oko lojo popo nipinle Eko, Lagos State Traffic Management Authority,
LASTMA ti le awon osise to to ogun duro nitori iwa ajebanu, atawon iwa to n
doju ti ajo naa.
Osise Lastma |
Gege bi AWIKONKO se
gbo, Ogbeni Mahmud Hassan to je olori awon to n ri soro awon araalu leka ajo
naa lo soro naa sita laipe yi pe kii se pe ajo LASTMA mon on mo da awon eeyan
naa duro, sugbon awon iwa to n doju ti ajo naa lo fa idaduro won.
O ni lara awon
igbese ti ijoba ipinle Eko fee gbe lati se atunse awon amuye lo faa, ki ajosepo
to dan monran si le wa laarin awon osise ajo naa atawon araalu, paapaa awon to
n gbe oko won rin loju popo.
O so pe opo igba
lawon ti pe won si akiyesi, tawon si ti kilo fun won pe ki won sora se, sugbon
se ni won ro pe ko seni to le mu awon, eyi lo fa ti igbese naa fi waye.
Bakan naa lo so pe
kii se awon ogun yi nikan ni ajo naa da duro, awon ogun miran wa ti ajo naa
jawe lo gbele e fungba die, titi di igba ti won yoo fi se awon atunse kan.
No comments:
Post a Comment