Labake pelu aso FCMB lorun |
Gege bi
AWIKONKO se gbo, won ni osan ojo naa leyin ti Labake to wa ni ipele karun (SS2,
Art) kuro nileewe lati maa lo sile, lo ri poosi naa loju ona, nigba to si ye e wo,
owo to to egberun mejidinlogun lo ba ninu e, iyalenu lo je fun un, aanu eni to
ni poosi naa si se, ko si mo bo se le wa eni to ni poosi naa ri.
Eyi lo je ko
tubo tu poosi naa, to si ri kaadi ti won fi n gbowo, iyen ATM eni to nii, loju
ese lodominrin Labake gba banki to wa lara ATM naa lo lati so fun won pe oun ri
poosi naa he, atipe ATM toun ri ninu e lo je koun woo pe o seese kawon osise
banki naa mo eni to nii.
Lakoko ti won fi han fawon ekegbe e |
AWIKONKO gbo
pe lesekese ti eni to je gege bi alakoso banki naa ti gba oruko Labake sile, to si seleri pe oun yoo
yoju si nileewe lojo keji lati daa lola. Sugbon nigba tawon toro naa soju won maa gbe oro
naa, se ni won n so pe egberun lona igba naira ni owo to wa ninu poosi ti Labake da pada.
Gbogbo bawon
eeyan se n gbo, ni won n fi tiwon kun un, ti won si n so pe egberun lona
eedegbeta, ati beebeelo lo wa ninu poosi naa, opo awon eeyan naa tun n sepe pe
lorisirisi.
Ko seni ti ko
gboro Labake nilu Sagamu lojo naa, bo tile je pe orisirisi oro aheso lo n jade
lati enu awon to n gbe iroyin naa kaakiri. Lojoru Wesde lakoko tawon omo ileeko
naa ti wa ninu kilaasi won la gbo pe awon osise banki naa de sile eko girama
tawon Musulumi naa, ti won si gba ofiisi oga agba, Ogbeni Oyenuga Davies lo
lati lo salaye.
Labake ati Iya e, Abosede |
Sugbon ko too
di akoko yi ni Oyenuga ti ranse si iya Labake, Arabinrin Abosede Samson pe ko
wa, awon osise banki fee ri, won si fee da omo e lola, inu obinrin naa dun, o si
gba ile eko Labake lo.
Okan lara
awon osise banki FCMB, Ogbeni Adefolurin to wa nibe lojo naa seleri wipe awon yoo fi oro naa to
awon oga agba patapata ni Banki won leti, ti awon yoo si fi ebun to joju ta
Labake lore fun ti iwa omoluabi to hu.
AWINKONKO
tun rii gbo pe loju ese lawon ore Labake ti bere sii jowu, nigba ti won
si se tan ni won bere sii ki ku oriire, awon kan ti e so pe se lawon
banki naa fee fun ni eto eko ofe lati fi daa lola.
Labake ati Arabinrin Isikalu |
Isikalu
sapejuwe Labake gege bi omo ti kii ja nileewe to si ja fafa lenu eko e, o wa lo
akoko naa lati gbawon akeko kaakiri orileede yi lamoran pe ki won fi ti Labake
se arikogbon nitori pe iwa rere leso omo eniyan. O loun mo pe ibi giga ni
Labake n lo.
Bakanna lo fi
kun oro e pe awon osise banki naa ti so pe awon yoo tun pada wa lati wa so esi
tawon alase ba fi fun awon lati le je ki araye gbo.
Iya Labake,
Arabinrin Abosede nigba to n ba AWIKONKO soro ni aago meji geerege osan oni, o
so pe inu oun dun fun iwa ti omo oun Labake hu nitori pe nnkan toun nigbagbo
ninu e nipe nnkan teeyan ko ba sise fun kii pe lowo eni, lara awon eko toun si n ko awon omo oun niyen.
Iya Labake, Labake ati Tisa e, Arabinrin Ajilore |
Labake ninu aso ileewe e |
O so pe looto
lawon ko yo, sugbon ebi ko pa awon nitori o ti to odun merin ti baba Labake ti
ku, to si je pe oun nikan loun n da gbo bukata awon omo oun, atipe Labake ni
akobi omo oun.
Bakanna lo
tun wa fi kun oro e pe awon osise banki naa ti so pe koun ati Labake yoju lojo
Aje Monde lati wa gbo esi abajade ipade tawon ba se pelu awon alase patapata
nileese banki awon.
AWIKONKO ko
nii da iroyin yi duro sibi, nitori eti to ba gbo alo, gbodo gbo abo e. Eku oju
lona.
No comments:
Post a Comment