Komisana olopaa Ogun kominu sawon agbebon to pa idile kan run - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, May 18, 2017

Komisana olopaa Ogun kominu sawon agbebon to pa idile kan run

Komosana olopaa nipinle Ogun, Ogbeni Ahmed Iliyasu ti kanminu sawon agbebon kan ti won wole pa idile musulumi kan run lagbegbe Atiba nijoba ibile Odoogbolu nipinle naa.

Komisana olopaa Ogun
Alaaji Sheikh Abdulsalam Yusuf Tanimola, iyawo e atawon omo e merin, Latifat Yusuf, omodun mewa; Ramat Yusuf, omodun meji atawon ibeji, Hamad Yusuf ati Muhammad Yusuf ti won lomodun mejo ni won lawon agbebon naa lo ka mole, ti won si ran won lo sorun apapandodo.

Nigba to n soro pelu omije loju lakoko to lo sabewo sawon ebi awon oloogbe naa, Iliyasu so pe o seni laanu wipe iru nnkan bayii sele loju oun atipe nilu toun ti je komisana, to si je pee mi ati dukia awon araalu lo je oun logun ju lo.

O wa seleri wipe oun yoo ri daju pe awon topinpin awon odaran naa, kawon si ri won mu lati jiya ese won nitori pe oun ko ri ipa tawon le so pe boya awon agbebon naa ja ilekun wole tabi ki won fo ferese wole.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI